IPOLONGO POETA-NÃO

Ni ẹnu ọ̀na ìyàrá tí gbogbo àkéwì-tí-kìí-ṣe-àkéwì aláṣùngbàgbé ngbé, ó yẹ kí a so àkọlé kán kọ́ sí tí o wípé: AKÉWÌ-TÍ-KÌÍ-ṢE-AKÉWÌ NṢIṢẸ́ LỌ́WỌ́. Ọwọ́ rẹ̀ ní àtúnṣe gbogbo ayé wà. Ọwọ́ rẹ́ yí kannáà ni ẹwá ìṣọdògún tí o tú àṣírí gbogbo àwọn aláìlóye ti wọ́n gbé òtítọ́ pamọ́ sì wà pẹ̀lú. Ọwọ́ akéwì-tí-kìí-ṣe-akéwì yí kannáà ni kọ́kọ́rọ́ ọ̀nà áti tún ayé ṣe gbé wà, òun sì ni o mọ ìyàtọ̀ láárín àwọn àkéwì-tí-kìí-ṣe-akéwì àti àwọn atúrọ́tà ọ̀lẹ̀ ọmọ ojo tí wọn kò jẹ́ki aye rójú.

AKÉWÌ-TÍ-KÌÍ-ṢE-AKÉWÌ gbọ́dọ̀ rí ìdánimọ̀ fún iṣẹ́ ribiribi rẹ̀ tí ó nṣe fún ire ara rẹ̀ nìkan: o mọ bí a ṣe lè fi ẹnu yaransọ́bẹ̀ dáadáa. O já fáfá débii gẹ́ẹ́ ti ọ̀rìnrìn kankan kò fi lè rín: gọ́lọ́gọ́ọ́ ni yío máa rìn bí adìyẹ̀ orí àba – ó kúkú mọ̀ pé òjò ti mpa igún bọ̀ ọjọ́ pẹ́!: ìdingbèri àrìnnàkò, ire gbogbo níi sójú owó bẹ́ẹ̀ni ojú ẹni máa là a rí ìyọnu.

Gbogbo aye gbọ́dọ̀ dá AKÉWÌ-TÍ-KÌÍ-ṢE-AKÉWÌ mọ̀ nípá ìlawọ́si rẹ̀ tí o njẹ́kí o ṣe àṣehàn ìṣẹ́ ìmọtaraẹninìkan rẹ̀ ní gbangba: gbogbo atótónu rẹ̀ ọ̀gbọ́n àti tọ́ mọ̀ndàrá lẹ́pọ̀n ni. Iṣẹ́ òun ìṣe. Ọlọ́fintótó ẹnu ù mi kálù. Ẹnudùnjíyọ̀.

AKÉWÌ-TÍ-KÌÍ-ṢE-AKÉWÌ ní àṣẹ láti jí láàrọ̀ gẹ́gẹ́bí olórin, òṣèrè, oníjó, atúnraṣe, ẹlẹ́ṣọ̀. Nípa àgbára tó ní láti tú àṣírí àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí, láti ṣọ ojú abẹ níkòó láìbìkítà: ìwà ìṣòdodo. Ìṣọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ gbọ́dọ̀ dá múṣémúṣé ni gbogbo ìgbà. TOJÚTÌYẸ́ LÀPARÒ FI NRÍRAN: ó gbọ̀dọ̀ mọ̀ pé ojúlásán kò ṣeé gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́; Nítóri ìdí èyí ni AKÉWÌ-TÍ-KÌÍ-ṢE-AKÉWÌ ṣe níláti ṣọ̀rọ̀ sókè láí bìkítá òun ti arayé yío wi.

AKÉWÌ-TÍ-KÌÍ-ṢE-AKÉWÌ a máa fi ìgbàgbogbo wípé òun kìí rìn lásán tàbi ni òun nìkan nítorípé àwọn alálẹ̀ mbẹ lẹ́hìn rẹ̀, ògbójú lóògùn ṣọmọ àjẹ́ níkòó: báyí ní ayé rí fún un nígbàti o ba di Akéwì-tí-kìí-ṣe-akéwì-àgbà , Akéwì-tí-kìí-ṣe-akéwì-ìyá, Akéwì-tí-kìí-ṣe-akéwì – tí kìí ṣe ìyá, Akéwì-tí-kìí-ṣe-akéwì – tí kìí ṣe ọmọ, - ti kìí ṣe òkun, a jẹ́ wípé ọ̀sà ni. Alagbalúgbú omi. Nínú òkun níkan ni ìdánilójú tí wà fún àkéwì pé kò dá wá kòsì dá rìn: gbogbo omi níí wárí fún Olókun, gbogbo ọnà ló wọjà. " ẹ káàbọ̀", o yá, gba àkéwì lọ́wọ́! Tẹ̀ẹ́ kío wọlé..(linkì láti wọlé).

Ana Maria Gonçalves

iluwẹ inu ile

lẹnu iṣé òun ìgbòyà láti dojúk ̣ ọ èyíkéyí ìpèníjà kí nsì wà ònà àbáy ̣ ọ – sótún àti sósì lati ̣ le ṣe àṣeyọri nípa fífi ìgbàgbogbo maa wá ìmúṣẹ àwọn èròñgbà ìmáyédẹrun ọmonìyàn  bíi: ètọ́ oníkálùkù, ìj ̣ ọba àparò-kan-kò-ga-jùkan-lọ, ìdájó òdòdo, ̣ abbl. tí mò tẹpẹlẹmó ̣ pèlú ìgboyà àti àibè ̣ rù òun àì ̣ ṣojo nigbàtí mo wà nínú ẹgbé ọ̀ ṣèlú alátakò. Bi nkan ṣe rí  lóni, kò dámilójú wipe ẹgbé náà tún ̣ ṣeé fọkàntán món láti jìjàgbara fún àw ̣ ọn mèkúnù. ̣ Èyíinì náà tó láti kọ ènìyàn lominú ṣùgbón kò y ̣ ẹ kí ènìyàn sọ ìrètí nù.

Níti eyín funfun bí ike tí o wà lẹnú mi, àjogúnbá lójé fúnmi láti ̣ ọwó àẉ ọn babañlá mí  aláwò dúdú tí Eledùà fí ara pípé dá ló ̣ lá tóbé ̣ ẹ̀ gé ̣ ẹ́ tí àw ̣ ọn amúnisìn ṣe dójúléwọn láti  kówọn lérú. Ì ̣ ṣèdá tí mo jogúnbá ò ̣ ún ló ̣ ṣọmi di ajìjàgbara tó dáñtó pè ̣ lú ò ̣ pọ̀ ḷọpò àpá ̣ lára à mi. Mo rántí wípé bàbá tó bími pàápàá gbá àìmoye àpá nínú ìjìjàgbara tirè náà ̣ débi wípé nígbàtí ọlójọ́ yío fi dé, eyín ̣ ẹnu rè nìkan ni kò tíí pàdánù tó fi kú. ̣

Nkan àràmbárà lèyí sì jé pẹ̀ lú. Ní ìgbà àkó ̣ kọ́ tí a pinu láti yí è ̣ yìn òkú rè ̣ padà tí a sì l ̣ ọ wú òkú rè jáde lé ̣ hìn ̣ ọdún márun, sí ìyàlénu wa, digbí sìni gbogbo eyín ̣ ẹnu rè wà síbè ̣ !. ̣ Kìí kúkú ṣe wípé ojú mì kòrókòró ní mo fí rí irúfé ìyanú bé ̣ ẹ̀ bíkò ̣ ṣe wípé àwọn àgbébojì ̣ tó wú òkú bàbá mi jáde ló nfunrere àrà méríìrí náà káyé. Èyí ló múkì ó dá tolóri-tẹlémi ̣ lójú wípé ẹnu ñnì tí Itamar fi máa nsọ ohun tó bá wùú nígbà ayé rè láláì bìkítà fún ̣ ohunkóhun tí àwón alágbárá lè fi òun ̣ ṣe kò díbàjé nítórípé ìjà gbogbo ìran alàwò ̣ dúdú ̣ ni Itamar gbékarí títí tófi dágbéré fáyé. Bíótíléjẹ́ pẹ́ òótó ̣ ọ̀ rọ̀ bí ìs ̣ ọkúsọ níí máa jọ létí  àwón ọ̀ bàyéjé ̣ . Èyí ló mú kí àw ̣ ọn kòlọ̀ rọ̀ ṣ̣í àwùjọ ṣọjú mọ baba mi tobéẹ̀ gẹ́ ẹ́ nígbà ayé ̣ rè ̣ṣùgbón àwòdì tó wògbín kò ̣ rọ̀ ni ò ̣ rọ̀ Itamar jási fún gbogbo w ̣ ọn. Nni wón bá yára ̣ ñwòó ní àwòmójú. Eyín òun ̣ ẹnu òhún tí Itamar kúndùn làtí máa fí mu oògùn olóró ̣ kokéèni náà lo máa ñfi gé áwọn òbàyejé ̣ jẹ́ láìbìkìtà. Eyín ò ̣ hún wáa dí eyín ìkòokò ̣ àjẹranjeegun!  

Léyin ̣ ọdún métàdínlógún tí Itamar ti rèwàlè ̣ ạ̀ ṣà, kòtíìsí ojúmó kan tí ayùn bàbá mi kìí ̣ yùnmí nítorípé mo féràn rè ̣ púpò ̣ . Ọ̀ pọ̀ ìgbà ni mo máa ñ ̣ ṣe àférí rè ̣ lójúmó ̣ tí mo sì máa ̣ ñgbìyànjí láti mú inú baba rere tó bímilóṃ ọ dùn nípa ríríi dájú wípé funfun nini ni eyín  tí mo jogún lówọ́ baba mi Itamar wà nígbàgbogbo. Ìwùrí ñlá ló sì máa ̣ njé fúnmi láti ̣ ṣọ

létí aráyé wípé nkò gbé eyín mi dé òdọ̀ dókítà y ̣ ọyín-yọyin rí kí ñmá bá dójuti àwọn  babañlá mí láti ilè Áfíríkà tí wó ̣ n jogún irú eyín tó lówúra bíi tí àwó ̣ n ̣ ọmọ ìyà wa ní ilé ̣ Nàìjíríà áti Kéñyà tàbí ilè ̣ Sàró níbití àyè ̣ wò DNA s ̣ ọpé ìdìlé wa ti ṣè wá. Èyí jé ̣ ohun ̣ àmúyangàn gidigidi fúnmi wípé àwọn ìran tí ara wọn dápé tí egungun wọn le kákááká bí  akọ òkúta ní àwà bá tan, kìí ṣe àwọn akúrẹtè ènìyàn! ̣

Èmi gégẹ́ bi ènìyàn aláwò ̣ dúdú nílè ̣ Brasil, mo m ̣ ọ pàtàkì ìwádì ìpilèṣ̣è ìran mi mó sì ̣ nífè sí orírún mí láti ilè ̣ Áfíríkà wá jú ipa bíñtín tí mo rí gbà láti ò ̣ dọ̀ ìran aláwò ̣ funfun ̣ nípaṣè àẉ ọn ìwé ìdánimò tí àwó ̣ n baba mi àgbà rígbà ní Museu do Imigrante (ile ìkó ̣ nkan ìsèmbáyé àwó ̣ n àtò ̣ húnrìnwà sí) tí ó wà ni ìlú tí a gbé bími tíí ̣ ṣe São Paulo ati àwọn  ìwé èrí míràn tí a jogúnbá ló ̣ wọ́ àẉ ọn apákan ìdílé wa to jé tí òyìnbó amúnisìn. Láìsí ̣ àní-àní, ìwé ìrìnnà ọmọ ìbílè Italia níyelórí ló ̣ jà àgbáyé ju eyín funfun bí ike ti mo ̣ jogúnbá lódọ̀ àẉ ọn ìran mi láti Áfíríkà lọ, ṣùgbón ó dámilójú wípé onjé ̣ ikán lásán-làsàn ̣ ní páálí náà yío pàdà jásí nígbèhìn tí eyín ike mi yío sì wà síbè ̣ -síbè ̣ . Òdodo ò ̣ rọ̀ . ̣

Gégẹ́ bí ènìyàn aláwò ̣ dúdú tó tún ní ìwé ìrìnnà ilè ̣ Beljiò ̣ mù, ó r ̣ ọrùn fúnmi láti ṣe àkàwé  láàrin ìran ènìyàn dúdú áti ìràn ènìyàn funfun. Èyí ló fúnmi ní àñfààní láti lè sòrọ̀ ̣ àsọdánu nípa nkan tí o lè wúwo díè ḷ ẹnu àwọn elòmíràn. Enu mi gbàá láti sòrọ̀ lórí ̣ ìyannijẹ àti ìjẹgàba. Nítèmi kò sí òrọ̀ kankan tí o jé ̣ èèwò ̣ rárá. Mo lè wú kúlè ̣ -kúlè ̣ ọ̀ rọ̀ ̣ bó bá ṣe wùmí. Kò sì sẹni tólè dámi lékun ̣

Èyi ni o dúró gégẹ́ bi àjogúnbá tó níyelórí jùl ̣ ọ fúnmi.  

Bí mo ṣe ní òrẹ́ aláwò ̣ dúdú ni mo ni aláwò ̣ funfun láìbìkítà fún ohunkohun. ̣ Èmi gangan ní ògbójú-lóògùn-sọmọ-àjé-níkòó!: ̣

Ẹ wá, èyin ̣ ọmọ ìyáà mi, ká dìjọ pawópọ̀ ká ̣ ṣayé bótiyè, ̣

Ẹjéká y ̣ ẹ ọkàn wa wò, ká lè ṣayé ire.

Yàtòssí eyin àtí oju ti mo fi j ̣ ọ bàbáà mi Itamar, mó tún jogún lára wọn ìwà àkíkànjú.

Anelis, osu kẹwàá ọdun 2020

Òṛ ọàṣẹ, álàyé ògbifò àti bé ̣ ẹ̀bẹ́ ẹ̀ ḷ ọ lábúlé ItamÁfrica

Pìpè láwá á peri akọni ti Itamar Assumpção jé láàrin wa nígbà tó wà láyé, Òun tí ìtànsàn ̣ ògo rè hàn gbañgba láárìn áwùj ̣ ọ nípa ìkéde ohun ti kò le kù láti ìrandéran. Ògbòlogbòó  Nego ti ọwójà rè ̣ kò ̣ ṣeé fẹnuṣọ, yéḅ ẹyèḅ ẹ ni ònà tí a lè gbà túmò ̣ rẹ̀ pín sí. À lè túmò ̣ rẹ̀ ̣ lónà aj ̣ ẹmó ìgbà áti agbàra, láláì lo èdè; láláì ló at ̣ ọwódá tábí àgbékalè ̣ ọ̀ rọ̀ ; bóyá a kàn lé ̣ lo èka ìpìlè ̣ ọ̀ rọ̀ òun gbólóhùn, nínú èyí tí gbólóhùn tí n ̣ ṣàpéjúwe ara ènìyàn dúdú, ara  èyí ti á fi rúbọ tí a sì tí ipa rè gbá ̣ ọjó ìwájú òun àtubò ̣ tán túntún fún gbogbo ̣ ẹni tí o bá  gbèrò láti mọ rírì ìgbé ayé rè — tòun ti agedeñgbe ogun rè ̣ lọ́ wọ́ , tíí ̣ ṣe àmì òun ohun èlò  àgbélèṛọ tó múnádókó láti fún ìṣèdá ohun tuntun àti ìmúr ̣ ẹwà iṣé ̣ọwó aláìlé ̣ gbé ̣ tí o mbá ̣ omi Osanyin jáde. Itamar tí à nsòrọ̀ rẹ̀ yìí ni Itamar tí ó wà ni agbedeméjì ayé òun ò ̣ run, ̣ èyí tí o jásí òkannáà. Òun náà ní a fé ̣ ̣ṣe àfihàn rè bí ewì aládùn fún ayé gbó ̣ , ọ̀ rọ̀ ewì tí ̣ ngbénú ẹran ara láláì jókòjéẹ́ , ọ̀ rọ̀ ìjìnlè ̣ oníga méjì tó kalè ̣ sí ìkóríta mé ̣ ta àlá àró ̣ ọ̀ rọ́ tán ̣ olóòrùn òdòdó. Ó yé lẹ́ ni àá polongo fáráyé gbó ̣ kí té ̣ rút ̣ ọmọ lé mò àrà tó tí gbélé ayé dá ̣ tí òkìkì rè fí gbòde tóbé ̣ ẹ̀ , nípá èyí tí ó fi ̣ ṣèdá ̣ ọjó ọ̀ la tuntun (láti inú ì ̣ ṣàn èjẹ̀ àkòkò yìí), ̣ èyí tí òun wé lójàá, tó sì wò ̣ lẹ́ wù tuntun ìmú ̣ ṣeré, nípa èyí tí ó fí gbé ògo àtinúwá hàn  nínu ìmò ìjìnlè ̣ onj ̣ ẹ àfibó orí òun ̣ ẹlédàá, orí àpééré-a-yàn-mámò ̣ , orí à ̣ ṣẹ (tí Itamar fún  ní orúkọ àdàpè Isca de Polícia – ìjẹ ọlópàá). Itamar lédè yorùbá túmò ̣ si gbani-gbani ló ̣ jọ́ ̣ ìjà. A tún lè pèé ní àkàndá èdá tí àw ̣ ọn òrìṣà “ránwá láti sòkalè ̣ wáá wòràn è ̣ dá” lákò ̣ tun ̣ nínú ìtàn ìgbésí ayé aláwò dúdú, èyí tí ó farahàn ló ̣ nà àrà. Yàtò ̣ sí ilé ìkó nkan ì ̣ ṣèmbáyé ̣ sí i tí ẹgbé olórin tí a mò ̣ si Filhos de Gandhi ni ìlè ̣ Bàhíà, èyí tí a fi ̣ ṣọ orí Itamar  Assumpção yìí ní ó jé àkókọ́ irúfé ̣ ilé bé ̣ ẹ̀ tí a yà ̣ ṣótọ̀ fún ò ̣ ḳ ọrin aláwò dúdú ní gbogbo ̣ ilè Brasil. Fún ìdì èyí, a lè ̣ ṣe àpèjúwe ipa pàtàkì tí èdè yorùbá kó ní àkójọpò ìgbé ayé ̣ ìran aláwò dúdú ní gbogbo agbègbè ilè ̣ àtìpó tí ó sì dúró gé ̣ gẹ́ bí òpómúléró fún gbogbo ̣ ìpèdè tí o tí ilè Áfíríkà jáde wa nípàtàkì àw ̣ ọn ìpèdè tí ó so èsìn pò ̣ mó ̣ ìjìjàgbara òun ìfè ̣ ̣ inú. Bí a bá fí etí sílè gbó ̣ ohun tí Itamar nfí orin wí nínú àw ̣ ọn àwo rè bíi Zózimo tí ̣ àkọlé rè jẹ́ “Alma no olho” (ojú è ̣ mí), ketekete ní aó máa gbó ̣ èdè Ò ̣ yọ́ , tí Ketu, ti ̣ Ìdòọ̀ mì, ti Kongo, ti Ndongo, ti Haiti, ti Cuba, ti ilè ̣ Amé ̣ ríkà pàápàá, ti ilè ̣ Brasil àti bé ̣ ẹ̀ ̣ béẹ̀ ḷ ọ. Ni ìlú kíló-mbò-lókè-tílè ̣ -ò-gbà ti Itamar tè ̣ dó sí, Beatriz ati ìpèdè “ntu” ̣ ẹnu rè ̣ nṣe àkáwé pàtàkì ayé e láyípo tí ìtàn òun òmìnira fi ìdì rè múlè ̣ gé ̣ gẹ́ bi ì ̣ ṣégún lórí ikú … ̣Láìsí àníàní… Beatriz tí á nwí yìí ní o dúró gégẹ́ bí ìpilè ̣ ṣ̣è (Nascimento) fún ìjìjàgbara tí ̣ Itamar wáá gbé kanrí títí di àmídékun òun ìgòkè (Assumpção) tí àwà ̣ ọmọléhin w ̣ ọn sì  ntèlé gé ̣ gẹ́ bí ìmó ̣ lẹ̀ ìgbàlà sínú ayé tuntun láláì fí ti ìj ̣ ọba ológun, ọlópàá tábi ò ̣ ṣèlú ṣe.

Tiganá Santana

Ìgbèsì Ayé tó lápẹẹrẹ

Ògá ̣ ọlópàá wòmíwò: ̣ "Orúkọ mi ni Benedito João dos Santos Silva Beleléu. Mo tún ni  orúkọ ìnagijẹ tó pò jáñtìr ̣ ẹrẹ bíi Vulgo Nego Dito, Nego Dito Cascavé (Paramólẹ̀ )̣ abbl. Mo yánjú arákùnrin ọmọ aláìgbóràn kan ní agbègbè ̣ Paraná láìpé yìí pè ̣ lú ìb ̣ ọn mi ti ñró “pá, pá, pá, pá!”

Nkan ọdún 2000 ni ìgbà àkókọ́ tí mo gbó ̣ àwo orin Itamar, ̣ ọmọ ọdún marùndínlógun  péré ni mo jé nígbànáà. ̣ Orin rè ọ̀ ún wò ̣ mi ní Akínyè ̣ mi ara tóbé ̣ ẹ̀ gẹ́ ẹ́ ti mo fi gbé ò ̣ ṣùbà  ràbàñtà fún irú òḳ ọrin tí ẹléẹ̀ dà fún ní irúfè ̣ ohùn tó já geere ̣ béẹ̀ tí o fi lè máa k ̣ ọ àwọn  orin aládùn béẹ̀ ní èdè p ̣ ọtugí tó já gaara.

Soft Power (ọgbón ̣ ẹrọ) ni àwọn olóyìnbó npe irúfè orin bíi èyi tí ó nlo ò ̣ rọ̀ aládùn láti fi ̣ sò òkò ìbànújé ̣ sí ̣ àwọn òbàyéjé ̣ àwùj ̣ ọ. O hàn dájúdájú wípé Soft Power gbáà ni gbogbo  orin Itamar Assumpção jé láwùj ̣ ọ òṣèlú wa. Ohun tí o fi ìdì èyí múlè ní ̣ ọnà èrọ̀ tí ò ̣ ḳ ọrin  náà ngbà láti fi ẹnu témbé ̣ lú ̣ àwón ìwà ìbàjé ̣ tí o j ̣ ẹmó ìyannij ̣ ẹ ẹléyàmè ̣ yà láwùj ̣ ọ wa.  Sùúrù òun èlẹ̀ tí Itamar fi ntó ̣ kasí àwó ̣ n ìwà ipá nínú orin rè ̣ jẹ́ ̣ọnà tó bùáyà tí ó sì múkí  gbogbo òrọ̀ rẹ̀ ẉ ọnilárá bámúbámú.

Àmó ̣kìí ṣe iṣé orin Itamar nìkan ló wúmi lórí. ̣ Nítèmi, añjòọ̀ nú pátápátá ̣ tí ngbé inú  aféfẹ́ ni mo kàá si ̣ . Pèlùpè ̣ lù ì ̣ ṣọwó korin ̣ rè tó faraj ̣ ọ afro-futurista ti Sun Rá túnbò jẹ́ ki ̣ orin rè ẉ ọnilétí dáradára. Òun alára páapáa kò kèrẹ̀ ḷ ọmọkùnrin, ìdùró rè wúnilórí yéye, ̣ ìwọṣọ rè sì bá ìgbà mu régírégí. ̣ .

Mo wòye pé èmi nìkan kó ni mo ríí bé ̣ ẹ̀ . Ị ṣé mánigbàgbé ti Itamar gbé ̣ ṣe ran àwọn aláwò ̣ dúdú aláìléníkan ló ̣ wọ́ j̣ ọjọ. Orin rè jẹ́ ìwúrí òun ìtùnú fún ̣ àwọn tí nwá òmìniran tòótó ̣ àti àṣeyọrí láwùjọ. Nípà àkitiyan Itamar àti ti àwọn aṣaájú miràn, àwọn aláwò dúdú náà ̣ lé “sòrọ̀ sókè” láwùj ̣ ọ. Àt’ọkùnrin àt’obìnrin, àt’ọmọdé àt’àgbà ni wón ti ní ìgbòyà làti ̣ wọ irúfé ạ ṣọ sórùn tabi ̣ ṣe irun tó wùwón sórí láàrin ìgbòrò làibè ̣ rù itú tí àwó ̣ n ̣ agbófìnwó lè fíwón pa. Láìsí àníàní, ìbè ̣ rù tí dínkù fún gbogbo aláwò ̣ dúdú láti ̣ yọ sí  ìgboro tí ìwọṣọ òun ìrìnsì wọn sì ti di àgbéyèwò òun àwòkó ̣ ṣ̣ e fún gbogbo gbòò láwùjọ.

Kádúpé kà si lu Itamar ló ̣ gọ̀ ọ́ ̣ẹnu fún ìgbòyà rè làti jìjàgbara ̣ nípa fífi orin rè kéde ìwà ̣ ìbàjé òun àìbìkìtà fún è ̣ tọ́ ̣ọmọnìyàn tí àwón ̣ ọlópàá àti àw ̣ ọn àjọ abánigbéorinjáde ilè yí ̣ gbéwò bí è ̣ wù. Nípa èyi ni Itamar fi jé ̣ ki ó yé tolórí-t ̣ ẹlémù wípé ìyàpàdà p ̣ ọn dandan kìí  sìi ṣe èèwò rárá fún ̣ ẹnikéni láti gbìyànjú è ̣ wò. Lóni, gbogbo wa ni a rí ̣ Itamar gégẹ́ bi ̣ àmì òmìnira kúrò nínú oko ẹrú ìjọba amúnisìn tí kò fé imí áw ̣ ọn aláwò dúdú rí láwùj ̣ ọ.

Nínú orin kan tí àkọlé rè njé ̣ “Vá cuidar de sua vida” (Fálànà gb ̣ ó tìè ̣ !) tí wó ̣ n lò nínú ̣ àwòrán Geraldo Filme, Itamar ménuba ìdojúk ̣ ọ tí àwọn aláwò dúdú nrí ̣ ni àwùjọ wa.  Bákannáà, akitiyan rè láti ríi wípé ayé gb ̣ ẹdẹmukẹ fún t’ẹru-tọmọ náà tún jẹyọ nínú  sinimá “Vida de artista” (Igbesi ayé òḳ ọrin) tí Itamar gbé jáde. Wàyi o, láàrin gbogbo  orin Itamar, àwọn èyi ti mo féran jùl ̣ ọ ni àwọn orin olólùfè bíi: “Tua Boca” ( ̣ ẹnu  aládùn), “Finalmente” (latàárò)̣. Béẹ̀ ni ̣ “ Milágrimas” (omijé ayò)̣ náà kò gbéyìn rárá ̣ nitorípé orin náà má ñtùmilára lákòókò tí mo bá njẹ ìrora nkan òsù mi lákọlákọ.

Kí nma puró, ̣ ṣeni àwọn orin Itamar máa nṣemí bí ẹnipé mo ngbádùn ìfẹnukonu to  l’óyinládùn. Ewì àtàtà sìnì gbogbo orin rè ọ̀ ún jásí léti ì mi. ̣ Ti mo bá ti ñgbó orin ̣ Itamar, jàin ní ara à mi máa ndìde ti ori mi a sì máa wú. Nítèmi o, ìtumò aláìlé ̣ gbé ̣ ti orin ̣ Itamar ní fúnmi kòseéfẹnusọ. Ko sí èyí tó ṣeé fi ọwó rọ́ ̣ṣéhìn nínú gbogbo i ̣ ṣé òun ̣ ìgbésí ayé Itamar. Fún ìdí èyí, mo ní ìdánilójú wípé èkọ́ nlá ndúró de gbogbo ̣ ẹni tí ó bá  wá ṣe àbèwò sí Ilé ìkó nkan Ì ̣ ṣèmbáyé Itamar Assumpção tí a fí ìdí rè ̣ lọ́ lẹ̀ sórí è ̣ ṛọ ayélujára yìí.

Ẹ wá, ẹjéká pawó ̣ pọ̀ gbé orúk ̣ ọ Itamar lárugẹ!. Itamar yẹ ni ẹni àápónọ́ nle ̣ (lana, loni àti  lójọ́ gbogbo ̣ !). O yẹka lu àwón ̣ ọmọ rè lọ́ gọ̀ ̣ẹnu fún ohun manigbàgbé tí wọn fi lólẹ̀ yìí ̣ ní ìràntí baba tóbiwọn.

Músò méta to rinlè ̣ fun ̣ Museu virtual Itamar Assumpção! (Ilé ìkónkan Ìṣèmbáyé Itamar ̣ Assumpção). Músò, músò, músò!


Mônica Ventura

PÀTÀKÌ MUSEU ITAMAR ASSUMPÇÃO  

Ní ìwòye tèmi, pàtàkì pátápátá ni irú Ilé Ìkó Nkan Iṣèmbáyé si tí a fí s ̣ ọri Itamar  Assumpção jé fun ìránti irú akíkanjú bé ̣ ẹ̀ . ̣

Gégẹ́ bí ò ̣ ḳ ọrin pàtàkì àti onímò kíkún tí Olódùmarè dáa, Itamar ̣ ṣiṣé mánigbàgbé nilè ̣ yí ̣ ni àwọn ọdún bíi 1970, 1980 tó ti kọjá lọ.  

Ní ilú ñlá bíi São Paulo – ìlú pàtàkì nínú orílè-èdè pàtàkì bíi Brasil, ríránti irúfé ̣ ènìyàn ̣ bíí ìtamar fihan pé ó kúrò ni ènìyàn yẹpẹrẹ.  

Béẹ̀ni, Itamar kì ̣ ṣe ẹni yẹpẹrẹ rárá.

Nitótípé bíótílèjẹ́ ènìyàn aláwò ̣ dúdú, ó fí ìyùn ló ̣ lẹ̀ gẹ́ gẹ́ bí ̣ ọlóp̣ ọlọ pípé èdá láwùj ̣ ọ ní  ìgbà ayé ré, ò sì típa ̣ ṣè bé ̣ ẹ̀ tún ìtàn ìran ènìyàn dúdú k ̣ ọ ní ilè Básìí. ̣

Gégẹ́ bí ènìyàn aláwò ̣ dúdú ni àwùj ̣ ọ São Paulo tí o jé ọ̀ kan lára àw ̣ ọn ìlú tí ìwà ìbàjé ̣ ẹléyàmè ̣ yà gbé gbilè ̣ jùl ̣ ọ, tí àwọn kòlọ̀ rọ̀ ssí kíi fé ̣ ẹ́ rí imí alàwò ̣ dúdú láàtàn, São Paulo, ̣ ìlú búrúkú níbítí ìwà ìkórira ṣodo si tóbéẹ̀ gẹ́ ẹ́ ti àw ̣ ọn olówò ẹrú ibè kòfi tètè dé ̣ kun nídì ̣ òwò búbúrú náa, ìlú tí kò tiè fún àw ̣ ọn àṣà ìran ènìyàn dúdú láàyè láti rí imú mí rárá, tí  àti ṣe ìbọ àwọn òrìṣà dí è ̣ṣè ñlá. ̣

Fún gbogbo ìdí tí a kà sílè wò ̣ nyí ní o ̣ ṣe ṣe pàtàkì kí gbogbo òḳ ọrin aláwò dúdú máa ̣ dúpé lọ́ wọ́ irúfé ̣ akíkanjú ènìyàn bíi ti Itamar tí o jíjàgbara fún w ̣ ọn tí o sì ṣílèkùn ̣ àñfààní ṣílè fún w ̣ ọn láti máa kọ orin wọn lọ láìbèrù àti láìbìkítà. ̣

Gbogbo wa náà ní a kúkú mọ bí o ṣe nírá tó fún ìran tí a dè ní ìgbèkùn làtí lè jàjàbó kí ̣ wọn tó wáa di ẹni tí nfọnrere àṣà ìbílè ẉ ọn lójútáyé gégẹ́ bí àw ̣ ọn ènìyàn dúdú ṣe ní  âñfààní láti máa ṣe lónìí ni ìpìnlè São Paulo. ̣

Ènìtí èyí kò bá yé tó, kí o lọ ka àwọn ìwé ìtàn bí àwọn amúnisìn tiṣe fi ojú àwọn aláwò ̣ dúdú rí póñpó ̣ nọ́ yan nílè ̣ yìí. Àìmoye foto ló sì wà láró ̣ wọ́ to lórí èyí. ̣

Gbogbo ohun tí èmí ròpò nìyí tí mo fi ̣ ṣe sàmósáñgúdù fún irú ìgbé ̣ ṣè akin tí Itamar ̣ gbélé ayé ṣe áti bí o ṣe fi iyùn lólẹ̀ . ̣

Mano Brown

Itamar Assumpção jé ọ̀ ḳ ọrin pàtàkí nígbà ayé rè. Bákannáà lósì tún jé ̣ kìígbó ̣ -kìígbà ̣ ajìjàgbara tíí máa fi orin rè kéde tábi funrere ìwà ìbàjé ̣ àẉ ọn òbàyéjé ̣ láwùj ̣ ọ. Èyí ló sì  sọó dí ò ̣ tá àw ̣ ọn alágbára ní ilè wa. Ojú rè ̣ rí pó ̣ ọ̀ npó ̣ náyan fún ìgbóyà rè ̣ , ó sì rí pípó ̣ n ̣ ojú àwón afé ̣ áj̣ ẹ-máféáyo tí wó ̣ n kún ilè ̣ wa dó ̣ ba. ̣

Béẹ̀ni gbogbo wa la mò ̣ itú tí àw ̣ ọn amúnisìn fí ojú aláwò dúdú rí ní ilè ̣ yìí láti ayé ìj ̣ ọba  pọtugi. Nigbànáà lóhùn, kòsí aláwò ̣ dúdú kankan tó tóo wójù òyìnbó nilè ̣ yìí kí gbórò ó ̣ má gbé irú ẹni béẹ̀. “Ỵ ẹẹsà!” sìní gbogbo èrú gbódò ̣ máa dáhùn níwájú olówó w ̣ ọn láyé  ọjóun. Ìlò o bólekú-kókú ní wó ̣ n nlo è ̣ rú láìbìkìtà, bé ̣ ẹ̀ sìni ò ̣ nà lójìn, ̣ ẹrú náà ní baba!.  

Àwọn tóbá jàjà ní èbùn orin láàrín àw ̣ ọn aláwò dúdú níláti r ̣ ẹ ara wọn sílè dáradára kí ̣ wón sì ríi wípé àw ̣ ọn kò fí tálèntì ò ̣ hún dá nkan rú láwùj ̣ ọ. Kódà, tí olówó ẹrú ní gbogbo  èrè tí irú táléntì bé ̣ ẹ̀ bá gbé jáde. Bé ̣ ẹ̀sìni irú ò ̣ ḳ ọrin béẹ̀ gbó ̣ dọ̀ ríi dájú wípé òún n ̣ ṣe jéjẹ́ ̣ láìparíwo kì orin òún sì yára jókòo légbé ̣ ̣ẹ Jègẹ̀ dẹ̀ tí olúwarè ̣ kòbá fé ̣ ẹ́ kan ìdin nínú iyò ̣ . ̣

Gbogbo irú ìwà báyìi ni Itamar lòdì sí tí ó sì dójú ìjà kọwón nípa fífí orin rè ̣ gbé ìran ̣ ènìyàn dúdú lárugẹ. Gégẹ́ bí ò ̣ rọ̀ babalori ̣ ṣà Sidnei Barreto, èyíkéyìí àláwò dúdú tó bá ti ̣ féẹ́ j̣ ẹun gbọin-gbọin ní àwùjọ wa gbódọ̀ ̣ṣetán láti tìlèkùn gb ̣ ọin-gbọin!. Nítorínáà ni  Itamar, tíí ṣe aláwò dúdú, ò ̣ ḳ ọrin tó dáñtó, olómìnirà è ̣ dá, ̣ ọmọ òrìṣà àtí ẹlésìn ̣ candomblé, tó nfi orin rè tọ́ ka ìwà ìbàjé ̣ láwùj ̣ ọ tí ó sì tún nlo ọgbón ì ̣ ṣèmbáye àw ̣ ọn  babañlá wa dí dándán kó rí pupa ojú àwọn òbàyejè ̣ aláwò ̣ funfun láwùj ̣ ọ wa. Jú gbogbo  rè ḷ ọ, ẹni á mbá nójà lááwò, ̣ ẹnìkan kìí wo ariwo òjà ní Itamar fí ò ̣ rọ̀ áẉ ọn ẹlégàn ilè ̣ yi ̣ ṣe, iṣé tiè ̣ lo k ̣ ọju mó tààrà-táárá. ̣

Eyí ló múki ọrukọ Itamar di manigbàgbé ti a sì fi ìdàsílè irú Ilé Ikó ñkan Ì ̣ ṣèmbáyé si yìí ̣ dáa lólá lé ̣ hìn ò ̣ pọ̀ ḷọpò ̣ọdún tó ti jáde láye. Ẹjéká ké músó, músò, músò! Fun Ilé Ikó ̣ ñkan Ìṣèmbáyé si tí Itamar Assumpção! Kí á sí lú àw ̣ ọn olùdásílè rẹ̀ ní ò ̣ gọ́ ̣ẹnu fún bí  wọn ṣe gbé irúfé nkan bàñtà-bañta báyìí kalè ̣ láti s ̣ ọ orúkọ Itamar di manigbàgbé..  

São Paulo, ọjó ḳ ẹèdọ́ gbò ̣ n osù ké ̣ san ̣ ọdún 2020.  

Djamila Ribeiro

Òrọ̀ bàntà, ò ̣ ̣ gbuuru. ̣

Iṣé akéwì i ̣ ṣé àmútò ̣ runwá ni. O dàbí ìpè làti òde ò ̣ run ti kò ̣ ṣeé ma jé, bi è ̣ nìyàn fé ̣ bó kò ̣ ̣ ó di dandan kó jéẹ̣ ni.  
Apẹẹrẹ tó fìdí èyi múlè pọ̀ jáñtir ̣ ẹẹ tí o fi ìdánilójú hàn gedeñgbe wipe, bíbí ní a mbí ènìyàn mó ̣ ị ṣé akéwì. È ̣ nìyàn léè kàwé jùbé ̣ ẹ̀ ḷ ọ, kí o ní òyé ju gbogbo akéwì ayé lọ,  láláìsí wípé a bí èbùn akéwì mó ̣ irú ̣ ẹni béẹ̀ , òtúbáñté ̣ lásán ni gbogbo atótónu rè ̣ yío jási. ̣
Lónọ̀ míràn è ̣ wẹ̀ ẹ̀ nìyàn léè jé ̣ akéwì kò má funra. A máa wáyé bé ̣ ẹ̀ lẹ́ ẹ̀ kọ̀ ọ̀ kan. ̣ Irúfé ẹ̀ nìyàn bé ̣ ẹ̀ kò wó ̣ pọ̀ , ̣ ṣùgbón wó ̣ n wà. Fun àp ̣ ẹẹrẹ Itamar.  
Léyìn tí o ti ̣ ṣe orísìrisì iṣẹ bí agbábóọ̀ lù, ò ̣ ṣèré ori ìtàgé, òḳ ọrin, onílù ti mọ nípa ìlo  orísìrísì ohun èlò orin, agbórinjókòó, áti béẹ̀ bẹ́ ẹ̀ ḷ ọ, Itamar kò fúnra rárá wípé iṣé ̣ aláròjinlè èdè ni orí òun yàn, nitorináà ló ̣ ṣe máa ñjiyàn wípé  
“poeta não” (èmi kìí ṣe akéwì!)  
Àmó o danilójú wípé è ̣ nìyàn tí o bá yan orí akéwì nìkan ni ó lè m ̣ ọ lílò òun àgbékalè ọ̀ rọ̀ ̣ béẹ̀ . ̣
Nínú orin rè tí ó pe àkòrí rè ̣ ní “Nego Dito Beleléu” (Ògbólógbò Beleléu) ati èyí ̣ tó pe  àkolé rèni ”Às Próprias Custas” (Ohun ojú wa lojú nrí), ó h ̣ àn gédéñgbé wípé Itamar ní  ìyáláya èbùn nínú ò ̣ pọ̀ ḷọpò ẹ̀ ka i ̣ ṣé bíi ò ̣ ṣèré orí ìtàgé, apàló tàbi òpìtàn, akò ̣ ròyìn, ̣ abbl  nítorípé Itamar férán láti máa k ̣ ọ ìtàn àròṣọ tàbí ìtàn àpilèḳ ọ, èyí jásí pé kò fi ìgbàkankan  dékun ìwé kíko. Ju gbogbo rè ̣ ḷ ọ èbùn òñkò ̣ wé áti akéwì rè ̣ tay ̣ ọ nínú ohun gbogbo tó  ñkọ éyí tó fíhàn dájúdájú wípé àkéwì tòótò lójé ̣ pè ̣ lú ògò tí kò lé ̣ gbé ̣ lónì, l ̣ ọla atí,  pàtàkìjùlọ, fún ọjó iwájú. ̣
Nítèmi, iṣé Itamar tó níyelórí jùl ̣ ọ ni Sampa Midnight (Ògànjó ̣ Sampa), mo fé ̣ ràn àwo ̣ òún débi gé ̣ ẹ́! Inú mi sì dùn wípé òun alára jé ̣ wọ́ fúnmi wípé àwo ò ̣ hún ni ààyò tiè ̣ náà. ̣
Ṣíbèsíbè ̣ nínú àwó ̣ n àwo tó tè ̣ lé èyí tí mo mé ̣ nubà lókè yìí, o hàn gbañgba wípé Itamar ̣ gbádùn ara rè dáadáa pè ̣ lù ò ̣ rọ̀ àròjinlè ̣ tó mú ò ̣ pọ̀ lọ̀ lọ́ wọ́ lọ́ pọ̀ ḷọpò nínú oniruurú è ̣ ka ̣ orin, yálà samba ní o, súféè-ñ-tàka, tàbi èka tí òun fúnrarè ̣ dá sílè ̣ tó sì fi òñtè ̣ tẹ̀ ẹ́ . Àw ̣ ọn  orin tó wúnilórí láìnílò òpọ̀ ḷọpò dò-re-mi ̣ ṣùgbón tí ariwo dùn gbó ̣ ngbó ̣ n bí ìtò ̣ ọ̀ mùtí ̣
Bí ilù rè ti rí náà ni orin rè ̣ rí létí aráyé pè ̣ lú. Orin tó ntuntun lójoojúmò ̣ letí aráyé. ̣
Párikegé gbogbo rè ni ò ̣ nà tí àw ̣ ọn orin rè ̣ṣe nkìlò ìwà tí ó sì nsamò ̣ nà nípà ìhùwàsí ̣ ọmọnìyàn lónà tó mú ìwúrí dáni. È ̣ yí tó fihàn irú è ̣ bùn tó ní. ̣
Ohun gbogbo nínú orin Itamar ló máa ñlọ léṣ̣òlẹ̀ ṣ̣ò bí ̣ ẹni fi ẹran jèḳ ọ.  
Itamar a máà kọrin bí ẹni tó ñsòrọ̀ ni. Bé ̣ ẹ̀ sìni ò ̣ rọ̀ rẹ̀ náà a máa jìnlè ̣ ju bí àw ̣ ọn èyàn ̣ ṣe  lérò lọ.  
Atínúdá rè a máà ní ìtumò ̣ to bùayà èyí tó le ̣ ṣòro láti gbámú fún ẹni tí kò bá funra.  
Nitorináà ní èmi ṣe nígbàgbó wípé àgbó ̣ ọ̀ gbó ̣ tán àti àgbó ̣ túngbó ̣ ni àw ̣ ọn orin Itamar,  nítorípé èdè rè jìnlè ̣ tóbé ̣ ẹ̀ gé ̣ ẹ́ tí ó fi ̣ ṣeéṣe fun láti ní ìtumò tó gíríkì fún àtìrandéran. ̣

Alice Ruiz

IÉ ÀTÍNÚDÁ ÌRAN ÈNÌYÀN DÚDÚ ̣

Ni orílè-èdè bíi tiwa, níbití gbogbo ènìyàn ti mò ̣ wípé ètò ò ̣ làjú wa níí ̣ ṣe púpò pè ̣ lú ̣ ìbáṣepò oun ìdàrapò ̣ onirúurú è ̣ yà ati à ̣ ṣà, yálà èyí ti o jé ti àw ̣ ọn òònilè nio, tabí ti aw ̣ ọn  àtòhúnrìnwá, o ̣ ṣe pàtàkì púpò lati máa fiyèsi ipa ti olúkúlùkù àw ̣ ọn èyà náà yàn láàyò, ̣ yálà lódidi nio, tàbí nípa ṣíṣe àyálò. Gégẹ́ bí aw ̣ ọn aláwò funfun tí w ̣ ọn wá láti Europa ṣe  kó ipa tó jọjú nípa ìdàgbàsókè ilè wa, bé ̣ ẹ̀ gé ̣ gẹ́ náà ní gbogbo àw ̣ ọn èyà yókù bí àw ̣ ọn  aláwò dúdú láti ilè ̣ Áfíríkà,àw ̣ ọn ará agbègbè ìlà oòrùn tí a mò si Ásíà ati àw ̣ ọn ọmọ onilè gan an tí a npè ni Ameríndia. Gbogbo àw ̣ ọn èyà òhún ló sì parapò ̣ láti jé ̣ kí o ̣ ṣeéṣe  fúnwa lati máa gbó tàbí lo àw ̣ ọn iró èdè àti gbólóhùn àimọye nínú èdè pọtugí tí àwọn  òyìnbó amúnisìn jogún fún orilè-èdè wa. Nípa báyìí, a ní ò ̣ pọ̀ ḷọpò ìpèdè, orin àtayébáyé ̣ àtí ìhùwàsí tí a jogún lati ọwó àẉ ọn orísìrísi ìran tí wón dàpò ̣ sínú è ̣ yà Brasil lónìí lára ̣ èyí tí a ti rí àwọn àjogúnbá tó bùayà gbáà  

Irú ile ìkó nkan ìṣèmbáyé si tí a fi ̣ ṣọri àwọn akíkanjú ọmọ aláwò dúdú wà láti ̣ ṣe àfihán  pàtàkí àtí lááríjà ipa takuntakun ti ìran aláwò dúdú kò láti ̣ ọwó àwó ̣ n agbédèga ìbìlè ̣ lórí ̣ gbogbo ñkan méríìrí bárọká tó gbílè ni ilè ̣ Brasil. ̣

Ile ìkó nkan ìṣèmbáyé sí ti Itamar Assumpção tí a gbé kalè ̣ sórí è ̣ ṛọ ayélujára wà gégébí  ònà kan gbòógì latí ̣ ṣe ìgbélárugẹ irúfé ̣ẹnìyàn pátàkì àti iṣé takuntakun tí a mò ̣ mó ̣ ọ̀ kan ̣ pàtákì nínú àwón ọ̀ ḳ ọrin tó gbajúmò jùlò ̣ ni gbogbo ̣ ọdún gbọọrọ tí àwa ìran ènìyàn ̣ dúdú fí njìyá lábé ìj̣ ọba amúnisìn tó jẹgàba ní ilè Bàsíì. Gé ̣ gẹ́ bí ò ̣ rọ̀ Paulo Leminski tí ̣ Itamar fí kọrin nínú orin aládùn tí o pe àkolé rè ní Memória preta (Akítíyan è ̣ nìyàn ̣ dúdú): “ẹ ma dámi lékun rárá nídì àjààgbulà mi. ̣ Ẹ jékí ñjìjàgbara, bí ñ o tiè ̣ kù, ìtàn yìó ̣ ràntí mi” púpò ̣ọgbón átinúdá ìran è ̣ nìyàn dúdú ló tipà ̣ ṣè orin Itamar fojúhàn tí o sì ̣ tókasí ònà àbáy ̣ ọ àṣeyọri aláwò dúdú. Èyí lo sò ̣ Itamar di orísun ìjìnlè ̣ agbárá àw ̣ ọn  babañla wa.  

Ile ìkó nkan ìṣèmbáyé sí ti Itamar Assumpção tí a gbé kalè ̣ sórí è ̣ ṛọ ayélujára wà láti jérìí ̣ ìpilè àti pàtàkí ìmò ̣ ati à ̣ ṣá ìjìnlè tí a jogúnbá láti ìlàméjì òkun ni ilè ̣ àẉ ọn babañla wa ki  o to dipé àwa náà tún ṣe àtúnrọ wọn fún ìwulò gbogbo àgbàyé àtí fún ìgbélékè ìran  aláwò dúdú. Kòmóòkun átí òdodo ò ̣ rọ̀ tó jìnlè ̣ gidi lo t ̣ ẹnu Ita ati Alice Ruiz jáde nígbàtí  wón k ̣ ọrin wípé “ìgbàkúùgbà tí ènìyàn dúdú bá ñs ̣ ọkún, omijé wa kòọ̀ kan to bá nkán silè ̣ ̣ a sì di ohun àràbarà tíí máa ṣe iṣé ìyanu”. ̣

Gilberto Gil.

“Aláwọ̀ dúdú ọmọ ilẹ́ Brasil aláìlábàwọ́ ni mó jẹ́” bayi gán ní Itamar Assumpção se júwe ara rẹ̀ ninu orin tó pe àkọle rẹ̀ ní Cabelo Duro (irun orí líle) nínú àwo rẹ̀ tí o sọ ní : Isso Vai Dar Repercussão (Gbogbo ayé lo máa gbọ́ èyí o) tí o ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Naná Vasconcelos. Èyí ló sì fi nṣe ápèjúwe ara rẹ̀ gẹgẹbí ènìyàn aláwọ̀dúdú tí a bí sí ilẹ̀ àtìpó níbítí ó gbé di dandan fún un láti má jẹ́ orúkọ aláṣopọ̀ bíi afro-brasileiro (ènìyàn àláwọ̀ dúdú ilẹ̀ Brasil) láláì pàdànú pàtàkì ìran rẹ̀ gẹgẹbi aláwọ̀ dúdú tọkàntọkàn. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn dúdú ní o lè gbójú-gboyà pé ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀ bíkòṣe ẹnítí o mọ rírì ọ̀kẹ́ àimọye ọdún tí àwọn babanlá ìran ènìyàn dúdú fí jìyà ni ilẹ̀ Brasil kí wọn tóo lé dì ẹni ara wọn.

Yálà o sèèsì tàbí kò sèèsì nío, Ìtá tíí ṣe àgékúrú orúkọ Itamar náà ni orúkọ tí wọn npe àwọn ọkọ̀ ojú omi ní agbègbè Brasil látijọ́, irúfẹ́ àwọn ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ onílẹ̀ máa fi nko èrò òun ẹrù láyé ijọ́un. Wọn a máa pe àwọn ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ ní Itagiba. Itapagé. Itahité. Itajubá. Itamar

Èyí ní o ṣọ ìtumọ̀ orúkọ Itamar gẹgẹbíi ọlọ́kọ̀ tí nlá ojú agbami nlá Atilantíìkì aláwọ̀ dúdú kọjá, tí o sì nwa ọkọ̀ rẹ̀ láti gbé àtubọ̀tán ìran rẹ̀ dé èbúté ògo. Gégébí a ṣe mọ̀, òrìṣà ní omi òkun tí o so agbègbè Áfíríkà pọ̀mọ́ agbègbè Amẹ́ríkà, híhó níí sìi máa hó nigbàgbogbo. Bákannáà, omi òkun ọ̀hún tún jẹ́ ìhà òun ìbùdó alábápàdé fún ogunlọ́gọ̀ ènìyàn gẹgẹbi ìkórítamẹ́ta àtapínṣẹ̀

“Aláwọ̀ dúdú ọmọ ilẹ́ Brasil aláìlábàwọ́ ni mó jẹ́” ni àkọlé àfihàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí a ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ láti sọ nípa ìgbésí ayé ògbóntárìgì ọ̀kọrin òun akéwì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ si Itamar Assumpção. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, o yẹ kí a ṣàlàyé lẹ́kùnrẹ́rẹ́ ìdí tí a fí gbé ètò áfíhàn náà kalẹ̀. Gẹ́gẹ́bí a ti mọ̀, irọ́ funfun báláú ni wípé ìlú Brasil jé párádísè fún gbogbo ẹ̀yà áti wípe àti aláwọ̀ dúdú àti fúnfún ní wọ́n ngbé ìgbé alàáfíá. Ìdí nìyí tí àfihàn yì ṣe gbèrò láti sọ ìtàn ìgbésí ayé Itamar tíi ṣe ọ̀kọrin aláwọ̀ dúdú tí a bí sí ìgbèríko tí o sì wá láti ṣiṣẹ́ ní ìlú nla São Paulo. O jẹ́ akíkanjú ọ̀kọrin tí kò bẹ̀rù ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Ní ilú náà yí ní o ti ṣiṣẹ́, tó ti gbéyàwó, tó sì bímọ. Láìsí àníàní, ènìyàn ẹlẹ́ran ara ni Itamar í ṣe tí o sì dojúkọ gbogbo ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara bíi tírẹ̀ náà dojúkọ ní ìlú náà láláì bárajẹ́ rárá. Ìgbésí ayé rẹ̀ dúró gẹgẹbíi dígí ìwòran fún ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ẹlẹ́ran ara bíi tirẹ̀ nípàtàkì jùlọ àwọn aláwọ̀ dúdú nípaṣẹ̀ àwọn orin átí ìhùwàsí rẹ̀. Gẹgẹbí àṣà ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí njẹ́ Tiganá Santana “Ògbólógbòó dúdú tó làmìnlaaka ni Itamar, ẹnití ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn” bẹ́ẹ̀ sìni iṣẹ́ rẹ̀ tayọ púpọ̀ láàrin gbogbo àwọn tí wọn nwádìí àjọṣepọ̀ tó wà “láàrín àsìkò tí a wá yí àti ìgbà ayé láíláí àwọn babanla wa”

Ìdì nìyí tí a fi ṣe àgbékalè àfihàn yìí gẹgẹbi àlàfibọ̀ àṣìkò bí ìkarahun ìgbín nínú èyí tí a ti rí àwọn kókó ọ̀rọ̀ lóri àtubọ̀tán ìran ènìyàn dúdú tí a kójọ tí a sì ṣe àfihàn rẹ̀ gẹgẹbi ìwé ìtàn, àwòran, fídíò, aṣọ ìmúra áti àwọn nkan àlò ojoojúmọ́ ti Itamar nigbá ayé rẹ̀. Bákannáà, a tún ṣe àkójọ àwọn iṣẹ́ mánigbàgbé tí Ita gbéṣe lókè eepẹ̀.

Ana Maria Gonçalves, Anelis Assumpção,
Frederico Teixeira e Rosa Couto.

Tẹ lati bẹrẹ
“Bí mo ṣe ní òrẹ́ aláwò ̣ dúdú ni mo ni aláwò ̣ funfun láìbìkítà fún ohunkohun. ̣ Èmi gangan ní ògbójú-lóògùn-sọmọ-àjé-níkòó!: ̣ Ẹ wá, èyin ̣ ọmọ ìyáà mi, ká dìjọ pawópọ̀ ká ̣ ṣayé bótiyè, ̣ Ẹjéká y ̣ ẹ ọkàn wa wò, ká lè ṣayé ire.Yàtòssí eyin àtí oju ti mo fi j ̣ ọ bàbáà mi Itamar, mó tún jogún lára wọn ìwà àkíkànjú.”
anelis assumpção
ka ọrọ kikun

1950

Ní ìgbà kan, (ìgbà kan nlọ, ìgbà kan mbọ̀ ọjọ́ ngorí ọjọ́!)
Ilẹ̀ a máa mì a sì máa gbin.
Èyí a máa dẹ́rùba àwọn ẹ̀da ènìyàn tí wọn npohùnrere ẹkún lábẹ́ ìjọba amúniṣìn
Ogunlọ́gọ̀ ló ṣègbé lọ́wọ́ ọ nínà ojoojúmọ́
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan, ìràpadà dé!
Ìtúsííẹ̀ dìde lẹ́hìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti kú láláì ní ìrètí.
Ṣùgbọ́n lẹ́hìn orẹhìn Zumbi dé, ìgbálà dé!

Àyọkà láti inú ijó ìbílẹ̀ Batuque, Às Próprias Custas S/A, 1981
 
Itamar Assumpção lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, Maria Aparecida, ní ọdún 1950.

1942 - Ataulfo Alves àti Mario Lago gbé áwo orin samba “Ai que saudades da Amélia“ jáde  1942 – A bí Jimi Hendrix1947 - Luiz Gonzaga gbé “Asa Branca” jádE 1942 - Ataulfo Alves àti Mario Lago gbé áwo orin samba “Ai que saudades da Amélia“ jáde  1942 – A bí Jimi Hendrix1947 - Luiz Gonzaga gbé “Asa Branca” jáde 1942 - Ataulfo Alves àti Mario Lago gbé áwo orin samba “Ai que saudades da Amélia“ jáde  1942 – A bí Jimi Hendrix1947 - Luiz Gonzaga gbé “Asa Branca” jáde 1942 - Ataulfo Alves àti Mario Lago gbé áwo orin samba “Ai que saudades da Amélia“ jáde  1942 – A bí Jimi Hendrix1947 - Luiz Gonzaga gbé “Asa Branca” jáde

Ni ọdun 1949 ni a bí Itamar de Assumpção* ni ìlú Tietê, ní ìgbèríko agbègbé São Paulo. Ibẹ̀ ní o gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ àgbá títí tí ó fi pé ọmọ ọdún méjìlá. Àwọn olóko òwò amúnilẹ́rú ni wọn dá ìlú náà sílẹ̀ nígbàtí wọn wọ àwọn ìgbèríkó lọ láti lọ fí tipátipá mú àwọn ọmọ onílẹ̀ lẹ́rú láti fiwọn ṣiṣẹ́ ìwakùsa góolù àti áwọn nkan àlùmọ́nì míràn. Ìlú ti à nwi yìí gbòòrò síi lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdun nípaṣẹ̀ àwọn aláwọ̀ dúdú tí wọn kó lẹ́rú lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti àwọn agbègbè míràn ni ilẹ̀ Brasil. Ọkan lára ọ̀ná tí àwọn aláwọ̀ dúdú fi máa npa ìrònú rẹ́ lóko ẹrú ní agbègbè ọ̀ún ni àwọn orin, ijó áti ìlù tí a mọ̀ si Batuques de Umbigada (Bàtúkì, ìjó aláfínúkónú). Irúfẹ́ eré bẹ́ẹ̀ tó wọpọ́ nígbàtí Itamar Assumção ndàgbà kó ipa tó jọjú nínú ìgbési aye rẹ̀ tí ó sí sọọ́ dí ìlúmọ̀ká òun gbájúgbájà òṣèré.

ISCA DE POLÍCIA (ÌJẸ ỌLỌ́PÀÁ)
àwọn ìlù òun ìjo Batuque (Bàtúkì) pẹ̀lu orísìrísìí aré ìgbafẹ́ láàrín àwùjọ áwọn aláwọ̀ dúdú tí kò jẹmọ ẹ̀sìn tábí àṣà òun ìṣe àwọn aláwọ̀ funfun jẹ́ nkan ìkóríra púpọ̀ nígbànáà tí àwọn ọlọ́páà agbèfọ́ba a sì máa fi pánpẹ́ òfin mú gbogbo ẹni tóba nṣe eré Bátúkì lágbègbè náà

Ní ọdún 1949 bakannáà ní a dá ẹgbẹ́ olórin Kànífà kan sílẹ̀ ni ìlú São Paulo ti a npe ní Grêmio Recreativo Cultural Escola de Samba Nenê de Vila Matilde.  Agbègbè ìlá-oòrùn ìlú São Paulo ní ilé ẹgbẹ́ náà kalẹ̀ sí, kòsì jìnnà sí ilé tí Itamar ngbé títí tó fi kú.

Ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950, Adoniran Barbosa ṣe àwo kan jáde nínú èyi tí ó tí kọ gbájúgbajà orin rẹ̀ tí o pe àkọle rẹ̀ ni “Saudosa Maloca” (Ayùn Aláìlẹ́gbẹ́). Àṣìkò yí kanáà ni Ataulfo Alves áti Elza Soares gbé orin aládùn wọn jáde ti wọn pè ní Bossa-Negra (Bọ́sá aláwọ̀ dúdú). Ní àṣìkò náà, ẹ̀rọ rédíò àṣọ̀rọ̀mágbèsì ní o gbayì júlọ ni àwùjọ̀, tí tolórí-tẹlẹ́mù máà nlò láti mọ ohun tó nlọ láwùjọ áti láti máa gbọ́ áwọn orin aládùn.

1* * * Itamar de Assumpção – orúkọ Àbíṣọ. Francisco José Itamar de Assumpção – orúkọ ìsàmì. Itamar Assumpção – orúkọ òṣèré

“Ó jèrè dùrù kéreké kan, ó sì fẹ́kọ́ọ, ṣùgbọ́n a kò ní ànfàní láti ra dùrù tuntun, ó sọ pé:
‘mo máa gbìyànjú èyí’. Lẹ́yìn náà ó bẹ̀rẹ̀.”

Ẹ̀dà ọ̀rọ̀ìyìn rere ti Maria Aparecida Silva de Assumpção ní ọdún 2003 fún fíìmù kékeré
kan tí àkọ́lé rẹ̀ń jẹ́“Beleléu Cá Entre Nós- Itamar Assumção antes do Nego Dito”, láti
ọwọ́ Fábio Giorgio.
Ní 1956, ọdún tó saájú àwo Itamar àkọ́kọ́, ẹgbẹ́ eléré Sociedade Amigos de Vila Matilde gbé ọkọ̀ eré kánífà àkọ́kọ́ jáde.
Ijó ìbílẹ̀ Batuque de Umbigada lásìkò tí wọ́n nfinúkonú ni Rio Claro, ọdún 1955. Fọ́tò láti ọwọ́ Rodolpho Capriva. Orísun: Museu histórico pedagógico (Mùsọ́ọ̀mù onítàn tí ó wà lábẹ́ Museu Amador Bueno da Veiga.
Isca de polícia (Ìjẹ ọlọ́pàá)
àwọn ìlù òun ìjo Batuque (Bàtúkì) pẹ̀lu orísìrísìí aré ìgbafẹ́ láàrín àwùjọ áwọn aláwọ̀ dúdú tí kò jẹmọ ẹ̀sìn tábí àṣà òun ìṣe àwọn aláwọ̀ funfun jẹ́ nkan ìkóríra púpọ̀ nígbànáà tí àwọn ọlọ́páà agbèfọ́ba a sì máa fi pánpẹ́ òfin mú gbogbo ẹni tóba nṣe eré Bátúkì lágbègbè náà
Elza Soares nkọrin lóri ìtàgé ni nkan ọdún 1950.
Fọ́tò: Arquivo Nacional / Domínio Público

1951: Ijọba gbe Ofin Lei Afonso Arinos jáde láti fi òpin sí ìwà ìdẹ́yẹsíní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni ilẹ̀ Brasil 1952: Frantz Fanon gbé ìwé rẹ̀ “Peles Negras, Máscaras Brancas” jáde.1957: Orílè-èdè Gana di òmìnira1958: Edison Carneiro gbé ìwé “O Quilombo dos Palmares” jáde1959: Elza Soares gbé àwo “Se Acaso você Chegasse” ti Lupicínio Rodrigues jáde. 1951: Ijọba gbe Ofin Lei Afonso Arinos jáde láti fi òpin sí ìwà ìdẹ́yẹsíní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni ilẹ̀ Brasil 1952: Frantz Fanon gbé ìwé rẹ̀ “Peles Negras, Máscaras Brancas” jáde.1957: Orílè-èdè Gana di òmìnira1958: Edison Carneiro gbé ìwé “O Quilombo dos Palmares” jáde1959: Elza Soares gbé àwo “Se Acaso você Chegasse” ti Lupicínio Rodrigues jáde. 1951: Ijọba gbe Ofin Lei Afonso Arinos jáde láti fi òpin sí ìwà ìdẹ́yẹsíní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni ilẹ̀ Brasil 1952: Frantz Fanon gbé ìwé rẹ̀ “Peles Negras, Máscaras Brancas” jáde.1957: Orílè-èdè Gana di òmìnira1958: Edison Carneiro gbé ìwé “O Quilombo dos Palmares” jáde1959: Elza Soares gbé àwo “Se Acaso você Chegasse” ti Lupicínio Rodrigues jáde.

Ijó ìbílẹ̀ Batuque de Umbigada ní ìlú Tietê, SP.
Ivan Bonifacio
Itamar Assumpção ya fọ́tò pẹ̀lú aṣọ ìṣọ̀rí 'Quem sabe pode' (Embáláyà) nínú agbo eré samba ẹgbẹ́ onikánífà  Nenê da Vila Matilde, 1985. Fọ́tò: Oscar Barros

1960

Àkókò tó nípọn ní ọdún mẹ́wàá to bẹ́rẹ̀ ni 1960 jẹ́ fún ilẹ̀ Brasil, Ìjọba ológun ló kọ́kọ́ gbòde ni ọdún 1964. Nígbátí ó di 1966, ẹgbẹ́ ajìjàgbara aláwọ̀ dúdú dí fífi lọ́lẹ̀ ni ìlú Oakland, Kalifọníà lọ́hùn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ẹgbẹ́ Panteras Negras ní ìlú Amẹ́ríkà. Àsìkò yí kánnáà ní arábìnrin aláìnílé ọmọ aláwọ̀ dúdú kan tí njẹ́ Carolina Maria de Jesus tẹ ìwé rẹ̀ “Quarto de Despejo: Diário de uma Favelada” jáde, nínú èyí tí o tí se àpèjúwe ohun tí ojú aláìlẹ̀níkan àti àwọn ìdílé aláwọ̀ dúdú nri ni Ilẹ̀ Brasil.

1961 – ọdún tí Ita kó lọ sí ìlú Arapongas, tíí ṣe ìlú kékéré kan nítòsi Londrina, ní ìpínlẹ̀ Paraná níbítí ìyá àtí bàbá rẹ̀ ngbé nígbànáà. Ní ìlú yìí ló ti darapọ̀mọ́ ẹgbẹ́ eléré orí ìtàgé kán tí à npè ni GRUTA, Grupo de Teatro de Arapongas (ẹgbẹ́ òṣèrè tíatá ti ìlú Arapongas) lábẹ́ àkóso Nitis Jacon. Láti ìgbàyí wá ni Itamar tí bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú àwọn ètò ìtanijí pẹ̀lú orin kíkọ áti ere orí ìtàgé tí ó sọ ìlú Londrina di gbájugbajà. Nigbàtí ó wá nínú ẹgbẹ́ GRUTA, Itamar kópa nínú ere bíi Arena conta Tiradentes (Ní ìránti olóògbéTiradentes) níní èyí tí o ti ṣe ipò ajìjàgbára Tiradentes aláwọ̀ dúdú.

Abdias do Nascimento jẹ́ òṣèré, akéwì, òñkọ̀wé, oníṣẹ́ ọnà àti olùkọ́ní tó dántọ́, òun náà sí tún ni Olóṣèlú, ajìjàgbara òun àjàfẹ́tọ̀ ọmọnìyàn to múnámúnà jùlọ láàrín àwọ́n aláwọ̀ dúdú ilẹ̀ Brasil. Fọ́tò: Arquivo Nacional / Domínio Público
ISCA DE POLÍCIA (ÌJẸ̀ ỌLỌ́PÀÁ)
Ní àsìkò ìjọba ol   ógun, tí ìwà ìpànìyàn òun ìnínilárá gbòde tí áwọn agbèfọ́ba npá áwọn aláwọ̀ dúdú ní ìpakúpa, ewu nlá ní fún ọ̀kọrin aláwọ̀ dúdú tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀sókè, nitorí ìdí èyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sá kúrò nílù kí wọn má báà fíwọ́n sòfò. Ni àkókò tí á nsọ̀ yìí, ẹgbẹ́ eléré orí ìtàgé aláwọ̀ dúdú ti Abdias do Nascimento da silẹ̀ láti ọdún 1944 tí a mọ̀ si Teatro Experimental do Negro (TEN) nílati kógbá wọle nítóri òfin kẹ́lẹ́nusọ́nu AI-5 tí ìjọba ológun gbe jáde ni ọdún 1968 nígbàtí Abdias do Nascimento fúnra rẹ̀ níláti sá kúrò nílù. Ni ọdún 1967, Milton Nascimento gbé àwo kan jáde ti o pè ni Travessia (Ìrékọjá). Ọ̀kan pàtàkì ni ọ̀kọrin yi jẹ́ẹ̀ nínú àwọn tí Itamar fẹ́ràn jọjọ.
Ami ti Ẹgbẹ Black Panther, AMẸRIKA, 1966
 
Carolina Maria de Jesus níbi ìkọ̀wé. Orísun: UOL/ Divulgação.
 
Isca de Polícia (Ìjẹ̀ ọlọ́pàá)
Ní àsìkò ìjọba ol   ógun, tí ìwà ìpànìyàn òun ìnínilárá gbòde tí áwọn agbèfọ́ba npá áwọn aláwọ̀ dúdú ní ìpakúpa, ewu nlá ní fún ọ̀kọrin aláwọ̀ dúdú tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀sókè, nitorí ìdí èyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sá kúrò nílù kí wọn má báà fíwọ́n sòfò. Ni àkókò tí á nsọ̀ yìí, ẹgbẹ́ eléré orí ìtàgé aláwọ̀ dúdú ti Abdias do Nascimento da silẹ̀ láti ọdún 1944 tí a mọ̀ si Teatro Experimental do Negro (TEN) nílati kógbá wọle nítóri òfin kẹ́lẹ́nusọ́nu AI-5 tí ìjọba ológun gbe jáde ni ọdún 1968 nígbàtí Abdias do Nascimento fúnra rẹ̀ níláti sá kúrò nílù. Ni ọdún 1967, Milton Nascimento gbé àwo kan jáde ti o pè ni Travessia (Ìrékọjá). Ọ̀kan pàtàkì ni ọ̀kọrin yi jẹ́ẹ̀ nínú àwọn tí Itamar fẹ́ràn jọjọ.
 
Igbasilẹ aworan ti Pin lati Santos FutebolClub ti Itamar lo, 2020

1960: Maria Carolina de Jesus gbé ìwé “Quarto de Despejo - Diário de uma favelada”  jáde ní BRASIL1960: Célia Cruz – Gbájúgbajà olórin Cuba - CUBA1962: Katherine Johnson, Dorothy Vaughan àti Mary Jackson ṣe gudugudu meje lofurufu – Ilẹ̀ AMẸ́RÍKÀ 1962: Ilẹ̀ Algeria di òmìnira kúro lábẹ́ ìjọba Faranse 1966: Clementina de Jesus gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde1969: James Brown kórin “Say It Loud, I'm Black and I'm Proud” 1960: Maria Carolina de Jesus gbé ìwé “Quarto de Despejo - Diário de uma favelada”  jáde ní BRASIL1960: Célia Cruz – Gbájúgbajà olórin Cuba - CUBA1962: Katherine Johnson, Dorothy Vaughan àti Mary Jackson ṣe gudugudu meje lofurufu – Ilẹ̀ AMẸ́RÍKÀ 1962: Ilẹ̀ Algeria di òmìnira kúro lábẹ́ ìjọba Faranse 1966: Clementina de Jesus gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde1969: James Brown kórin “Say It Loud, I'm Black and I'm Proud”

Itamar Assumpção gẹgẹbí akíkanjú ajìjàgbara Tiradentes, ẹgbẹ́ òṣèré GRUTA, Londrina, PR. Orísun: Ìwé ìròhìn Folha de Londrina.
Itamar Assumpção níbi àjọ̀dún Festival Universitário ní Londrina. Orísun: Ìwé ìròhìn Folha de Londrina
Itamar Assumpção, Neusa Pinheiro àti Arrigo Barnabé ní àsìkò tí wọ́n nkorin níbi Àjọ̀dún orin Festival de Música Popular tí ọdún 1979. Orísun: TV Tupi

1970

“... Dudu kan wa ni Paulista
Breu ko si Trianon
Nibo ni Itunu naa wa? ”...

Akosile lati Sampa Midnight, Sampa Midnight, 1985

Ní ọdún 1973 - Itamar Assumpção kópa ní àjọ̀dún orin tí a mọ̀ sí Festival Na Boca do Bode tí o wáyé ni Ilé ìfihán eré orí ìtàge ni fasitì Londrina (Teatro Universitário da Universidade Estadual de Londrina (UEL).

Ní Londrina yí kanáà ni ákọlé Isca de Polícia (Ijẹ ọlọ́pàá) gbé jẹyọ nígbàtí wọ́n ju Itamar sẹ́wọ̀n nídìí wípé wọ́n ká ẹ̀rọ ìgba òhùn sílẹ̀ kan mọ́ọ lọ́wọ́ tí o jẹ́ ti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Domingos Pellegrini.

Ọdún 1973 ni Bob Marley ati ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ The Wailers gbé áwo àkọ̀kọ́ - Catch a Fire (Gbanájẹ) tí o sọ ẹ̀ka orin Reggae tí ìlú Jamáíkà di gbajúgbajà láwùjọ àgbáyé jáde, èyí tí o sì ran dé ilẹ̀ Brasil páapáa ni ìpínlẹ̀ Maranhão.

Ní àkókò yí kannáà ni Elizena kódé agbègbè Penha tí o sì bẹ̀rẹ̀síi ṣe iṣẹ́ takuntakun ní gbogbo ìpínlẹ̀ yí.

ISCA DE POLÍCIA (ÌJẸ ỌLỌ́PÁÁ
Orin reggae tí o jẹyọ púpọ̀ nínú iṣẹ́ Itamar jẹ́ orin tí o nííṣe púpọ̀ pẹ̀lú ìgbésí ayé àti ìṣe àwọn ènìyàn tí a kàsí àrúfin àti ọ̀dàlúrú láwùjọ tí àwọn àgbófinró sì máa nfi ìgbàgbogbo lé irúfẹ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ká. Èyí kò yọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ka orin aláwọ̀ dúdú ni ilẹ̀ yìí bíi samba, funk tábi hip hop sílẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá a sì máa fi ìgbàgbogbo lé áwọn ti nkọ irúfẹ́ orin bẹ́ẹ̀ k
Trecho do Documentário ClassicAlbums: Catch a Fire, 1999

Ni ọdún 1975 ni Itamar Assumpção ṣe ìgbeyáwó pẹ̀lú Elizena Brigo tí òun náà si kólọ si Penha láti máá gbé níbití o gbé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ apínwèé ilé IPTU lábẹ́ ìjọbá ìbílẹ̀ São Paulo.

Lẹ́tà kan tí Itamar kọsi aya rẹ̀ Elizena
Àwọn ìbùdó ìtọ́niòsọ́nà fún iṣẹ àtúnṣe ọkọ̀ ojú irin nítòsí afárá Viaduto do Chá. Orísun: Ijọba ìbílẹ̀ São Paulo
 
Fọ́tò Vale do Anhangabaú ní 1970
 
Ita òun Zena ni nkan ọdún 1970
 
Isca de Polícia (ìjẹ ọlọ́páá
Orin reggae tí o jẹyọ púpọ̀ nínú iṣẹ́ Itamar jẹ́ orin tí o nííṣe púpọ̀ pẹ̀lú ìgbésí ayé àti ìṣe àwọn ènìyàn tí a kàsí àrúfin àti ọ̀dàlúrú láwùjọ tí àwọn àgbófinró sì máa nfi ìgbàgbogbo lé irúfẹ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ká. Èyí kò yọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ka orin aláwọ̀ dúdú ni ilẹ̀ yìí bíi samba, funk tábi hip hop sílẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá a sì máa fi ìgbàgbogbo lé áwọn ti nkọ irúfẹ́ orin bẹ́ẹ̀ k
Atokan lati Awọn awo-orin Alailẹgbẹ Iwe-ipamọ: “Catch a fire”, 1999

“Mo fun ni gbogbo akoko yii
Kolu ni enu
Nwa fun ibi aabo kan, asomọ kan, ibi ipade kan
Igbiyanju lati opin de opin
São Paulo
Lati ẹgbẹ si ẹgbẹ
Ninu ogun ti alaafia, iderun, tabi iku paapaa ... ”

Akosile lati Embalos - Sampa Midnight, 1985

1970: Pelé di agbábọ́ọ̀lù tí gbayì jùlọ lágbàyé ní ìdíje Ife ẹ̀yẹ àgbáyé Copa do México 1970: Miles Davis gbé àwo “Bitches Brew” jáde1970: Tim Maia gbé àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde1973: Luiz Melodia gbé àwo “Pérola Negra” jáde1977: Àwòrán sinimá Blacula àti Blackenstein jáde láti ọwọ́ àjọ Blaxploitation 1974: Jorge Ben gbé àwo “Tábua de Esmeralda” jáde1974: Fela Kuti gbé àwo “Alagbon Close” jáde 1977: A dá ẹgbẹ́ Black Rio sílẹ̀ 1970: Pelé di agbábọ́ọ̀lù tí gbayì jùlọ lágbàyé ní ìdíje Ife ẹ̀yẹ àgbáyé Copa do México 1970: Miles Davis gbé àwo “Bitches Brew” jáde1970: Tim Maia gbé àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde1973: Luiz Melodia gbé àwo “Pérola Negra” jáde1977: Àwòrán sinimá Blacula àti Blackenstein jáde láti ọwọ́ àjọ Blaxploitation 1974: Jorge Ben gbé àwo “Tábua de Esmeralda” jáde1974: Fela Kuti gbé àwo “Alagbon Close” jáde 1977: A dá ẹgbẹ́ Black Rio sílẹ̀ 1970: Pelé di agbábọ́ọ̀lù tí gbayì jùlọ lágbàyé ní ìdíje Ife ẹ̀yẹ àgbáyé Copa do México 1970: Miles Davis gbé àwo “Bitches Brew” jáde1970: Tim Maia gbé àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde1973: Luiz Melodia gbé àwo “Pérola Negra” jáde1977: Àwòrán sinimá Blacula àti Blackenstein jáde láti ọwọ́ àjọ Blaxploitation 1974: Jorge Ben gbé àwo “Tábua de Esmeralda” jáde1974: Fela Kuti gbé àwo “Alagbon Close” jáde 1977: A dá ẹgbẹ́ Black Rio sílẹ̀

Tọkọtaya Zena òun Itamar Assumpção ní ọjọ́ ìgbeyàwó alárédè wọn ni kóòtù
Itamar òun Zena lórí ibùsùn pẹ̀lú Serena, ọmọ wọn ìkókó, 1977
Itamar Assumpção, Zena ati Serena ọmọ, 1977
Àwọn ebí àti ọ̀rẹ́ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó Zena òun Itamar Assumpção
Celina nígbàtí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn a
Àwọn lẹ́ta áfọwọ́kọ láàrin Zena òun Ita

1980

Ní ọdún 1980, Itamar gbé àwo orin Beleléu Leléu Eu (Èmi Beleleu Leléu) jáde láti ọwọ́ ilé iṣẹ́ Lira Paulistana, èyí sí sọ Itamar di gbajúgbajà olórin tí gbogbo ayé nwári fún.

Itamar tipaṣẹ̀ àwọn orin rẹ̀ di gbajúmọ̀ láwùjọ o sí dì ẹni tí tẹrutọmọ nwáríi fún ní ilẹ̀ Brasil láláì ká wípé o jẹ́ aláwọ̀ dúdú sí.

Orin Beleléu dí orin àtẹnudẹ́nu tí gbogbo ènìyán fẹ́ràn nílẹ̀ Brasil ti orúkọ Itamar Assumpção sì di nlá nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, nípàtàkí nítorí ìwúnilórí tí o fi ngbé àwo orin náà kalẹ̀ áti ẹwà àwòrán ẹ̀yìn àwo orin rẹ̀. Bakánáà túnni àwọn olólùfẹ́ Itamar kìí fí eré rẹ̀ ṣeré rárá nítorí ẹwa ijó àti orin Itamar.

Gbogbo ọná tí Itamar ngbà korin áti jó pẹ̀lú àwòrán tó fanimọ́ra tó máa nwà lẹ́yìn àwọọ́n àwo orin rẹ̀ jẹmọ àṣà iṣẹ́ ọnà tí a mọ̀ si afrofuturista lásìkò náà.

Orin ákọ́kọ́ tí o fi èyí hàn nínú àwo Itamar ni “Nego Dito” nínú èyí ti Itamar ti sọ ìtàn nípa ọ̀dọ́mọkùnrin aláwọ̀ dúdú kan tí ìwà rẹ̀ fi ara pẹ́ ti Itamar fúnra rẹ̀ tobẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Itamar fi funra wípe ara rẹ̀ lófi korin.

Ni ọdún 1987, Nego Dito dí orin àtúnkọ láti ọwọ́ ẹgbẹ́ olórin samba rock tí njẹ́ Branca di Neve nínú àwo tí wọ́n sọ ni Branca Mete Bronca (ẹgbẹ́ olórin Branca gbójú agan).

“Inu bi mi, mo ja
Mo ṣe ki o ṣẹlẹ
Mo ṣiṣe
Mo pa ejò náà, mo sì fi ọ̀pá náà hàn
Lati ṣe afihan rẹ si ẹnikẹni ti o fẹ lati rii ati fihan
Orukọ mi ni
Benedito João dos Santos Silva Beleléu
Nego Dito, Nego Dito cascavé”

Àtúntẹ̀ páálí àwo orin Beleléu Leléu Eu, 1980
Ìwé àjọṣepọ̀ láàrín Itamar àti ilé iṣẹ́ Selo Lira Paulistana fún ágbéjáde àwo orin Beleléu Leléu Eu
 
"Èmi kò ní sùúrù òun ìrètí aláìnídìí bíi tíyín. Kò dàbí ẹnipé ẹ̀yín mọ bí nkan ṣe nlọ nílẹ̀ yí, nítórí tí o bá ṣepé ẹ bá mọ̀ ní, ẹ̀bátí máa retí ìjọba oní dọ́gbandọgba. Tí ẹ̀yín bá mọ̀ ni, ẹ̀ bá jà fún ẹ̀tọ́ yin lágbàyé ju báyìí lọ. Ìdí èyí ní mo ṣe wípé alálàá ní gbogbo àwa aláwọ̀ dúdú nílẹ̀ yìí, àti ẹ̀yin àti èmi alára páapáa. Alálàá ni gbogbo wa. Ṣùgbọ́n àbá níi di òótọ́, ojo ni kìí jẹ́kí a dáa. Àlá ti èmi nlá, àlá ìjìjàgbara ni... Èmi rí ará à mi gẹgẹbí ẹ̀bùn fún ìran yìí láti ọwọ́ áwọn babanlá wa”.

Ọ̀rọ̀ láti ẹnu Sun Ra nínú sinimá Space is the place (ọ̀lẹ níkan lààyè ò gbà), 1974"
 
Parliament-Funkadelic, ní ọdún 1970
 
Awọn gilaasi jigi ti Itamar, 2020
 
Itamar ati Alzira E kọrin lakoko iṣafihan kan ni Funarte. Fọto: Vange Milliet
Itamar Assumpção lóri ìtàgé ni teatro Paulistana. Fọ́tò: Nícia Guerreiro
Igbasilẹ igbasilẹ lati Beleléu Via Embratel ni Nosso Estúdio,
São Paulo, 1981. Aworan: Renato Mascaro
wé lórí àwo orin Beleléu Leléu Eu, 1980
   
▶   OUÇA
   
ISCA DE POLÍCIA (ÌJẸ ỌLỌ́PÀÁ)
Beleléu tí Itamar yàn láàyò bíì ẹ̀dá àtọwọ́dá rẹ̀ jẹ́ ènìyàn tí a le sọpé o kó gbogbo ìwà “ìbàjẹ́” tí àwọn afẹnubaníjẹ́ máa nránnúmọ́ lára àwọn aláwọ̀ dúdú. Itamar ṣe éyí láti le fihan irú irọ́ funfun báláú tí gbogbo rẹ̀ jásí àti bí àwọn aláwọ̀ dúdú kìí tí ṣe èyàn bẹ́ẹ̀ rárá. Èyí ló sì mú kí gbogbo ènìyàn nífẹ̀ ẹ Beleléu ọ̀hún dọba.

“Ojú rè ̣ rí pó ̣ ọ̀ npó ̣ náyan fún ìgbóyà rè ̣ , ó sì rí pípó ̣ n ̣ ojú àwón afé ̣ áj̣ ẹ-máféáyo tí wó ̣ n kún ilè ̣ wa dó ̣ ba.”
DJAMILA RIBEIRO
ka ọrọ kikun

Yàtọ̀ sí àwo tí Itamar Assumpção àti ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ Isca de Polícia (ìjẹ ọlọ́pàá) gbé jáde, wọ́n tún ṣe ọ̀pọ̀ eré ìta gbangba ní Teatro Lira Paulistana láti ṣe ìfílọ́lẹ̀ àwo orin náà. Ọ̀nà àrà ní wọ́n fí ṣe ibití eré náà gbé wáyé. Wọ́n kọ́ orí ìtàgé náà ó dábí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Beleléu òun àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sì wà ní “ìhàmọ́”. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti wọn bá Itamar korin ọ̀ún ni Denise Assunção, Suzana Salles, Vânia Bastos, Luiz Chagas, Paulo Lepetit, Gigante Brazil, Virgínia Rosa àti Rondó.

Lira Paulistana jẹ́ Ilé tíátà tí o fi ààye gba orísìrísìí òṣèré láì wó irúfẹ́ orin wọn. Irú ilé eré bẹ́ẹ̀ ló sì fi ààyé gbá àwọn ọ̀kọrin tí a mọ̀ sí Vanguarda Paulista (Àsíwájú Olórin ni São Paulo) títí dí nkan ọdún 1980. Ni ọdún yìí kannáà, Arrigo Barnabé gbé àwo orin rẹ̀ Clara Crocodilo jáde, èyí tí o sì sọ ọ́ di gbajúgbajà olórin ni São Paulo gẹ́gẹ́bí tí Itamar Assumpção.

Àbáwọlé Ilé ẹgbẹ́ Lira Paulistana ni nkan ọdún 1980. Fọ́tò: Calil Neto

Ni ọdún 1980 náà tún ni Ita àti aya rẹ̀ Zena bí ọmọ wọn kejì tí wọ́n sọ ní Anelis Assumpção. Láti kékeré ni Anelis ti máa mbá bàbá rẹ̀ lọ sí ojú agbo ere àti ilé ìká ohùn òun orin silẹ̀, nígbàtí ó sì dàgbà, a máa bá baba rẹ̀ kọrin lórí ìtàgé.

Itamar, Anelis áti Iara Rennó lóri ìtàgé ní Crowne Plaza, 1998 Fọ́tò: Jairo Torres
Itamar Assumpção ati Arrigo Barnabé ninu fiimu naa “Lira Paulistana ea Vanguarda Paulista”, itan-akọọlẹ orin nipasẹ oludari Riba de Castro
 
Ẹya ti a ko gba aṣẹ ti disiki beleléu ti a ṣe ni Ilu Brazil pẹlu aṣọ “Japanese”, ti wọn ta ni Vila Madalena ni São Paulo
 
Isca de Polícia (Ìjẹ ọlọ́pàá)
Beleléu tí Itamar yàn láàyò bíì ẹ̀dá àtọwọ́dá rẹ̀ jẹ́ ènìyàn tí a le sọpé o kó gbogbo ìwà “ìbàjẹ́” tí àwọn afẹnubaníjẹ́ máa nránnúmọ́ lára àwọn aláwọ̀ dúdú. Itamar ṣe éyí láti le fihan irú irọ́ funfun báláú tí gbogbo rẹ̀ jásí àti bí àwọn aláwọ̀ dúdú kìí tí ṣe èyàn bẹ́ẹ̀ rárá. Èyí ló sì mú kí gbogbo ènìyàn nífẹ̀ ẹ Beleléu ọ̀hún dọba.
 
Àwòran páálí ẹ̀yìn àwo orin Clara Crocodilo, 1980.
 
Díẹ̀ lára àwọn fọ́tò Itamar Assumpção òun Anelis, 1990
Foto: Glória Flugel
 
Itamar ya fọ́tò pẹ̀lú Anelis, Mariana áti Ana Carolina ni ẹnu ọ̀nà àbáwọlé Museu do Ipiranga, c.1987
Aroko fọto nipasẹ Itamar Assumpção ati ẹgbẹ Isca de Polícia, 1983. Fọto: Oscar Bastos
Igbejade nipasẹ Itamar ati Banda Ísca de Polícia (pẹlu Suzana Salles ati Vânia Bastos), São Paulo, 1981. Aworan: Renato Mascaro.
Ìwé lórí àwo orin Beleléu Leléu Eu, 1980
   
   

Ni ọdún 1981 Itamar Assumpção àti ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ Isca de Polícia gbé àwo míràn jáde tí wọ́n pè ni Às Próprias Custas S.A. (Ọwọ́ ara ẹni) láti ọwọ́ Selo ISCA. Itamar fúnra rẹ̀ ló sì san gbogbo owó tí o fi gbé áwo náà jáde. Ojú eré tí Itamar àti àwọn ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ kọ ni Sala Guiomar Novaes tí o wà ni FUNARTE-SP ni wọ́n tí ká àwòran tí wọn sopọ̀ sínú àwo náa níbití wọ́n ti kọ àwọn orin lọ́kan ò jọ̀kan pẹ̀lú àwọn olórin míràn bíi os “desbundados” Jards Macalé àti Waly Salomão àti ẹ̀dà orin Noite de Terror (ọ̀gànjọ́ ìbẹ̀rúbojo) láti ọwọ́ Jovem Guarda tí gbajugbajà olórin nì Roberto Carlos náá ti fi ìgbàkan gbé jáde rí.

Ní ọdún 1983 Itamar Assumpção ṣe alábàpàdé tọkọtaya Alice Ruiz àti Paulo Leminski, ònkọ̀wé pàtàkí méjì ní ilẹ̀ Brasil tí wọ́n gbájumọ̀ bí ìsáná ẹlẹ́ẹ́ta nítorí àjọṣepọ̀ wọn nínú ajọ “geração mimeógrafo” àtí ẹ̀ya ewì níṣókí tí àwọn ará ilẹ̀ Jàpán npè ni haikais. Ìpàdé nàá só èso rere púpọ̀, òun ló sì bí áwo kẹta Itamar ti a pè ní, Sampa Midnight (Sampa lórú ọ̀gànjọ́)

Itamar áti Wally Salomão ni Funarte, osù kárun ọdún 1984. Fọ́tò: Jorge Rosemberg
Díẹ̀ lára àwọn fọ́tò Itamar pẹ̀lú Jards Macalé, 1987. Fọ́tò: Lita CerqueiraFoto: Lita Cerqueira
 
Band "Isca de Polícia" ni ifihan ti Ifihan ni FUNARTE - SP
 
Igbasilẹ fọto ti “Banda Isca de Polícia” aṣọ, 2020
Itamar Assumpção áti Leminski, 1988.
Fọ́tò: Lailson Santos

A gbé àwo Sampa Midnight jáde ní ọdún 1985 nígbàtí Itamar alárá ti fẹ́ ẹ́ kúrò nínú ẹgbẹ́ Lira Paulistana tí o kógbá wọlé lọdún yìí kan náà. Ogunlọ́gọ̀ orin aládùn ló kún inú àwo náà nínú èyí tí a ti rí "Z da Questão Meu Amor", "E o Quico?", "Sampa Midnight" áti  “Navalha na Liga” tí Itamar kọ nípa ṣíṣe àtúntò àwọn ewì Alice Ruiz. Ewì tí o fi síde áwo náà kó tóo wá kan orin   “Prezadíssimos Ouvintes” ni ewì “tuntun” (Novo) láti ọwọ́ Paulo Leminski.

Ohun tuntun kankan ko tún lè jọmi lójú mọ́, kò sóhun túntun lábẹ́ ọ̀run mọ́
Nkan kannáà ti a tí mọ̀ látijọ́ aláyétidáyé nipé
Adìyẹ a yé ẹyin a sì pa ọmọ kánnáà tuntun”

Ewì láti ọwọ́ Paulo Leminski ti Itamar ṣe àdàlò rẹ̀
Àtúntẹ̀ àwòrán ẹ̀yìn àwo orin Sampa Midnight, 1983
   
   
HQ tí a gbé jáde lóri orin Itamar, Brancalion, 2020.
 
Leminski, Itamar Assumpção, Serena, Fortuna ati Aninha duro fun fọto, 1987
 
Itamar òun Alice Ruiz nílé ìdáná Musicasa
 
Itamar Assumpção àti Alice Ruiz, 1994

“Aṣọ-ayọ ti ayọ
o ti kun
ṣofo”

Alice Ruiz
Itamar Assumpção, Isca de Polícia àti Anelis tí ó tẹ̀lé bàbá rẹ̀ lọ síbi eré nígbàtí ó wà ni ọmọ ọdún márùn péré, 1985

1982: Geraldo Filme gbé àwo “O Canto dos Escravos” jáde pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Clementina de Jesus àti Doca - BRASIL1982: Lélia Gonzalez gbé ìwé  “Lugar de Negro”, jáde pẹ̀lú Carlos Hasenbalg - BRASIL1987: Olodum gbé àwo “Egito Madagascar”  jáde- BRASIL1988: Sueli Carneiro dá ẹgbẹ́ Geledés - Instituto da Mulher Negra sílẹ̀ -BRASIL 1988: Ousmane Sembène gbé sinimá “Campo de Thiaroye” jáde - SENEGAL 1989: Spike Lee gbé sinimá “Faça a Coisa Certa” jáde- AMẸ́RÍKÀ 1982: Geraldo Filme gbé àwo “O Canto dos Escravos” jáde pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Clementina de Jesus àti Doca - BRASIL1982: Lélia Gonzalez gbé ìwé  “Lugar de Negro”, jáde pẹ̀lú Carlos Hasenbalg - BRASIL1987: Olodum gbé àwo “Egito Madagascar”  jáde- BRASIL1988: Sueli Carneiro dá ẹgbẹ́ Geledés - Instituto da Mulher Negra sílẹ̀ -BRASIL 1988: Ousmane Sembène gbé sinimá “Campo de Thiaroye” jáde - SENEGAL 1989: Spike Lee gbé sinimá “Faça a Coisa Certa” jáde- AMẸ́RÍKÀ 1982: Geraldo Filme gbé àwo “O Canto dos Escravos” jáde pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Clementina de Jesus àti Doca - BRASIL1982: Lélia Gonzalez gbé ìwé  “Lugar de Negro”, jáde pẹ̀lú Carlos Hasenbalg - BRASIL1987: Olodum gbé àwo “Egito Madagascar”  jáde- BRASIL1988: Sueli Carneiro dá ẹgbẹ́ Geledés - Instituto da Mulher Negra sílẹ̀ -BRASIL 1988: Ousmane Sembène gbé sinimá “Campo de Thiaroye” jáde - SENEGAL 1989: Spike Lee gbé sinimá “Faça a Coisa Certa” jáde- AMẸ́RÍKÀ

Ni ọdún 1988, Itamar tun ntẹ̀síwájú pẹ̀lù àjọṣepọ̀ tó lówúra èyí ló sì so èso rere nínú àwo Intercontinental! Quem Diria! Era só o que faltava!!! (Taló lé ròpé èyi á ṣeéṣe!) tí Itamar gbé jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀kọrin àjèjì tí a mọ̀ si Continental. Biótílẹ̀jẹ́pé àwo àkọ́kọ́ nìyí tí Itamar yíò gbé jáde láti ọwọ́ ilẹ́ iṣẹ́ aládàni, síbẹ̀síbẹ̀ ó ríi dájú wípé òun kò pàdànú òmìnira lórí iṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì kọ orin tó wùú lọ́kan bíi "Adeus Pantanal" (Ó dìgbàoṣe o, Pantanal) nínú èyítí Alzira àti Tetê Espíndola tí wọ́n jẹ́ ọ̀kọrin láti ìpìnlẹ̀ Mato Grosso do Sul ti kópa.

“Eu nasci e vivo no Brasil, então
Eu fui à Corumbá pra no Pantanal olhar a bicharada
E fui pra ver, não vi, que decepção senti
Vi quase nada”

Àyọkà láti inú orin Adeus Pantanal, Intercontinental! Quem Diria! Era só o que faltava!!!, 1988

Ni ọdún 1987 Gilberto Gil di olùdari àjọ agbáṣàga ìpìnlẹ̀ Bahia tí a mọ̀ si Fundação Gregório de Matos. Àjọ yìí wà fún ìgbégà àṣà aláwọ̀ dúdú. Ní àkókò ìṣàkóso tírẹ̀, Gilberto Gil gbíyànjú láti tẹpẹlẹ mọ́ àjọṣepọ̀ láàrín ìpínlẹ̀ Bahia àti ilẹ̀ Áfirika, èyí ló sí ṣe okùnfà dídásílẹ̀ Casa do Benin em Salvador (Ibùgbé Àṣà Orilẹ̀-èdè olómìnira Benin) ni ilù Salvador, bákanáà, ó tún dá Ilé Àṣà Bràsil ti a mọ̀ si Maison du Brésil silẹ̀ ni ìlú Ouidah ni oríilẹ̀-èdè Benin ni ilẹ̀ Áfíríkà lọ́hùn.

Báyìí ní ìṣàkóso Gilberto Gil tíṣe ṣe okùnfà dídá Ilé Iranti pàtàkì fún ìgbélárugẹ̀ àṣá ìran àwọn aláwọ̀ dúdú sílẹ̀ láti ṣe àfihàn akitiyan àwọn ọlọ́pọlọ pípé ọ̀kọrin àláwọ̀ dúdú ni ilẹ̀ Brasil.

“Irú ile ìkó nkan ìṣèmbáyé si tí a fi ̣ ṣọri àwọn akíkanjú ọmọ aláwò dúdú wà láti ̣ ṣe àfihán  pàtàkí àtí lááríjà ipa takuntakun ti ìran aláwò dúdú kò láti ̣ ọwó àwó ̣ n agbédèga ìbìlè ̣ lórí ̣ gbogbo ñkan méríìrí bárọká tó gbílè ni ilè ̣ Brasil.”
gilberto gil
ka ọrọ kikun

a Ní ọdún 1988, Itamar áti ọmọ ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ nínú àwọn tí a ti rí Paulo Lepetit, Gigante Brazil, Denise Assumpção àti Luiz Waack rin ìrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Jámánì fún ìgbà àkọ́kọ́ láti lọ kọrin ní orísirisi ìlú láti fi ṣe àmì àyájọ́ ọgọ́rùn ọdún tí a fi òpin si Òwò ẹrú ní orilẹ̀-èdè Brasil. A gbàwọ́n lálejò ní ìlú Kassel níbítí ètò ìfihàn iṣẹ́ ọnà ìgbàlódé ti wáyé. Lẹ́hìn náà ni wọ́n kọrísí àwọn ìlú bíi Hamburg, Berlin, Nuremberg, àti Bremen. Itamar ló ànfààní ìrìn ájò náà láti darapọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ọkọrin bíi tirẹ̀ ni ilẹ̀ Jámánì èyí sì yọri sí gbígbé jáde àwo orin rẹ̀ tuntun méji ní ìlú náà pẹ̀lú àtilẹhin Messidor, ilẹ iṣẹ́ agbórinjáde tó gbajúgbajà tí o sì lórúkọ,  lọ́dọ̀ ẹnití àwọn olórin bíi Piazzola àti Tito Puente náa tí máa ntẹ áwo jáde.

Itamar áti Denise Assunção níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ní ìlú Hamburg, 1989. TV Chroma

Àwọn ará Jámánì tẹ́wọ́ gba àwọn àwo méjèèjì pẹ̀lú ọ̀yàyà, kódà ìwé ìròhìn Hessisch-Niedersächsisch Allgemeine kọ àkọlé tó wúnilórí lóri àwo Itamar nínú èyí tí a ti ṣe àpèjúwe  orin Itamar gẹgẹbí “àṣeparí orin aládùn ilẹ̀ Áfíríkà“.

ISCA DE POLÍCIA (ÌJẸ ỌLỌ́PÀÁ)
Gẹgẹbí akọ̀ròyìn ọmọ Rio de Janeiro nì Felipe Tadeu tiṣe ṣe àpèjúwe Itamar nígbàtí wọ́n pàdé ni orílẹ̀-èdè Jámánì, Itamar áti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kò sàì rí ìyọnu ránpẹ́ nídìi orin áti àwo tí wọ́n ṣe ni ìlú òyìnbò náá nítorípé lẹ̀hìn tí wọn dári sí Hamburgo láti Berlim, ọlọ́pàá múwọn wọ́n sì ṣe àyẹ̀wo fínífíní síwọn lára lọ́kọ̀ọ̀kan láti mọ̀ bóya wọ́n gbé oògùn olóró wọlé. Itamar bínú sí ìwà ìdojúkọni tí àwọn ọlọ́páà Jámánì hù síwọn náà ó sì sọ̀rọ̀ sàkàsàkà sí ìjọba wọn: “Kílódé tíwọ́n fí dójúléwa? Ṣé torípé a jẹ́ aláwọ̀ dúdú ni?”
e brancos juntos?”.

Itamar Assumpção tún ni ànfààní láti padà lọ korin ni ilẹ̀ Europa ni ìgbà àìmoye tí ó sì mú Suzana Salles, Ná Ozetti áti Bocato lọ́wọ́ bí elégbè, ní ìgbàmíràn ẹ̀wẹ̀ ó tún mú Alzira Espíndola lọ, bákannáà ló si ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́méjì onígòjé tí a mọ̀ si violonistas Duofel.

“Irú ile ìkó nkan ìṣèmbáyé si tí a fi ̣ ṣọri àwọn akíkanjú ọmọ aláwò dúdú wà láti ̣ ṣe àfihán  pàtàkí àtí lááríjà ipa takuntakun ti ìran aláwò dúdú kò láti ̣ ọwó àwó ̣ n agbédèga ìbìlè ̣ lórí ̣ gbogbo ñkan méríìrí bárọká tó gbílè ni ilè ̣ Brasil.”
gilberto gil
ka ọrọ kikun
Itamar Assumpção kópa nínú ètò tẹlifisọ̀n Roda Viva pẹ̀lú Gilberto Gil, 1987
 
Itamar Assumpção ya fọ́tò ní iwájí àkọ̀lé “ẹ káàbọ̀ sí orílẹ̀-èdè Jámánì”, Fọ́tò: Vânia Toledo
 
Awọn ara ilu Brazil ti n kede irin-ajo Itamar si Ilu Jamani
Itamar ṣere pẹlu Duofel, 1988
Àtúntẹ̀ àwòrán ẹ̀yìn àwo orin Sampa Midnight, Messidor, Alemanha, 1988
Iwe kika siseto fun gbọngan Werkstatt gbọngan, 1988
Kaadi ifiweranṣẹ Itamar ranṣẹ si ẹbi, ti a tẹjade nipasẹ ile-iṣẹ igbasilẹ rẹ ni Jẹmánì
Isca de Polícia (Ìjẹ ọlọ́pàá)
Gẹgẹbí akọ̀ròyìn ọmọ Rio de Janeiro nì Felipe Tadeu tiṣe ṣe àpèjúwe Itamar nígbàtí wọ́n pàdé ni orílẹ̀-èdè Jámánì, Itamar áti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kò sàì rí ìyọnu ránpẹ́ nídìi orin áti àwo tí wọ́n ṣe ni ìlú òyìnbò náá nítorípé lẹ̀hìn tí wọn dári sí Hamburgo láti Berlim, ọlọ́pàá múwọn wọ́n sì ṣe àyẹ̀wo fínífíní síwọn lára lọ́kọ̀ọ̀kan láti mọ̀ bóya wọ́n gbé oògùn olóró wọlé. Itamar bínú sí ìwà ìdojúkọni tí àwọn ọlọ́páà Jámánì hù síwọn náà ó sì sọ̀rọ̀ sàkàsàkà sí ìjọba wọn: “Kílódé tíwọ́n fí dójúléwa? Ṣé torípé a jẹ́ aláwọ̀ dúdú ni?”
Àtúntẹ̀ àwòrán ẹ̀yìn àwo orin Intercontinental! Quem Diria! Era só o que faltava!!!, 1988
   
▶   OUÇA
   
Visite a loja e compre a reedição deste LP
Itamar Assumpção ati olorin Ná Ozzeti
Àwòran páálí ẹ̀yìn àwo orin Bicho de 7 Cabeças Vol. I Fọ́tò: Vânia Toledo
   
   
Àwòran páálí ẹ̀yìn àwo orin Bicho de 7 Cabeças Vol. II Fọ́tò: Vânia Toledo
 
Àwòran páálí ẹ̀yìn àwo orin Bicho de 7 Cabeças Vol. III Fọ́tò: Vânia Toledo
 
Oṣu Kẹta ti igbiyanju ya awọn oju ni aarin ilu São Paulo, 1992

1990

Ọdún mẹ́wàá tó bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun ni ọdun 1990 ní Itamar tún tẹ̀síwájú nínú ìjìjàgbara rẹ̀. Àsìkò yí ni o korin pẹ̀lú Rita Lee níní àwo tí wọ́n pè ní 'Só Vejo Azul' (Ojú mi nri bàìbàì) nínú àwo Todas as Mulheres do Mundo (Sí gbogbo obìnrin àgbàyé). Àjọṣepọ̀ láarin Itamar òun Rita Lee yìí di ti ọlọ́jọ pípẹ́ bí irú èyi tó wà láàrin Itamar òun Alice Ruiz, Alzira Espíndola, Vera Motta àti àwọn ọ̀kọrin míràn nípa èyítí Itamar fí ngbé ohùn àti ìṣẹ́ àwọn olórin obìnrin jáde.

Ẹ gbọ bí Alice Ruiz tise ṣe àpèjúwe rẹ̀: “ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jìnlẹ̀ tóbẹ́ẹ̀gẹ́ẹ́ tí o fí sọọ́ di manigbàgbé ẹ̀dá tí o nfi ìgbàgbogbo ṣe ìwùrí fáráyé. Ìtàn kòle gbàgbé Itamar láíláí”

O tilẹ̀ di àkókò kan tí o jẹ́ wípé kìkìdá obìnrin ni ọmọ ẹgbẹ́ olórin Itamar tí ó sì sọ orúkọ ẹgbẹ́ náà ni Orquídeas do Brasil (Òdòdò ilẹ̀ Brasil). Ẹgbẹ́ yìí tí o jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní ilẹ̀ Brasil ló bá Itamar kọrin nínú àwo alápapọ̀ mẹ́ta Bicho de 7 Cabeças (Iwin Abàmì olóri méje) tó jáde ni ọdún 1994.

Ẹgbẹ́ olórin As Orquídeas yìí kánnáá ló ṣe àfihàn ìfẹ̀ tí Itamar ní sí lílo ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú ohùn orin aládùn tí àwọ́n elégbè rẹ̀ bíi Simone Julian, Simone Sou, Clara Bastos, Tata Fernandes, Geórgia Branco, Nina Blauth, Miriam Maria, Adriana Sanches àti Lelena Anhaia fí òhun gáara gbé jáde.

Àwo alápapọ̀ mẹ́ta Bicho de 7 Cabeças (Iwin Abàmì olóri méje) tí Itamar gbé jádé lọ́dún náà ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Tom Zé, Jards Macalé, Alice Ruiz, Alzira Espíndola àti Paulo Leminski.

Ní àsìkò yí kan náà, Itamar tún ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ olórin mìràn yàtọ̀si Rita Lee nínú èyí tí a ti rí Ney Matogrosso, Cássia Eller àti Zélia Duncan tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà olórin MPB.

Yàtọ̀sí orúkọ nlá tí Itamar ní gẹgẹbí agbé orin kalẹ̀ àti alátúntò orin tó dántọ́ láìjẹ́pé o kàwé láti kọ́ iṣẹ́ náà níbikíbi, Itamar tún di ìlúmọ̀ọ́ká nípasẹ̀ ẹwà èdè rẹ̀ àti ìrínísí ọmọkùnrin tó ṣeé mú yangàn pẹ̀lú àwò ojú tó yàn láàyò òun aṣọ tó jẹ ojú nígbèsè tí ó máa nwọ̀ lórí ìtàgé. Zena aya rẹ̀ ló máa nran gbogbo aṣọ náà fun. Gbogbo nkan wọ̀nyi ní Itamar máa nlò láti wà ní dọ́gbandọgba pẹ̀lú àwọ́n ọ̀kọrin aláwọ̀ dúdú tó gbajúgbajù làgbàyé.

Talão de ingressos do show Bicho de 7 Cabeças
 
Itamar fihan pẹlu Tata Fernandes ni abẹlẹ ti orchid Ricardo Cukierman ni abẹlẹ, 1990s
 
Díẹ̀ lára àwọn fọ́tò tí Itamar Assumpção yà pẹ́lú u Rita Lee, 1993 Fọ́tò: Fernando Sampaio.
Tiketi ere si Teatro Ipanema
 
Itamar Assumpção ya fọ́tò pẹ̀lú ẹgbẹ́ olórin Orquídeas lóri ìtàgé Bicho de 7 cabeças ni SESC Pompeia, 1994. Fọ́tò: Rubens Chaves.
 

Ní ọdún 1995, Itamar tún gbé àwo orin míràn jáde nínú èyítí ó tí ló àwọn elégbé láti àárin àwọn ọmọ olórin Orquídeas àti Iscas. Àwo náá ni a pè orúkọ rẹ̀ ní Ataulfo Alves - Pra Sempre Agora (Ataulfo Alves – Láílái laó máa ṣe àfẹ̀ri rẹ̀). Nínú àwo náá ní Itamar ti ṣe àtúnkọ àwọn orin Ataulfo Alves, olórin samba tó múná dóko, lẹ́hìn tí Itamar tí fí eti sí àwọn orin rẹ̀ fún ọdún mẹta gbáko. Àwo yìí ní o fíhàn bí o tiṣe sòro tó láti ṣe àkàwé iṣẹ́ àti ẹ̀bùn Itamar láláì jẹ̀bi Beleléu.

Fọ́tò ojú Ataulfo Alves àti Itamar Assumpção, 1993. Àwòrán láti ọwọ́: Helcio Nagamine (Folha Imagem)

Ní ọdún 1998 Itamar gbé áwo rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde lórí àkọlé tí ó pè ni: Pretobrás I (Brasil Dúdú) – Por que que eu não pensei nisso antes? (báwo ni mío tíṣe ronú dẹ́bẹ̀ láti ìyé ọdún yìí o?! Ní ọdún yìí kánnáà, a fí àmì ẹ̀yẹ ọ̀kọrin tí mùsèmúsè rẹ̀ dá músémúsé jùlọ dá Itamar Assumpção lọ́lá láti ọwọ́ àjọ kán tí à npè ni Associação Paulista de Críticos de Arte, a APCA.

Báyìí ni Itamar ṣe di olórúkọ nlá láwùjọ àwọn akọrin lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn ní ilẹ̀ Brasil bíótílẹ̀jẹ́pé oníranù àti alákọrí ní àwọn kan kàá sí tí àwọn ilẹ iṣẹ́ agbórinjáde sì fí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún déye síi.

ISCA DE POLÍCIA (ÌJẸ ỌLỌ́PÀÁ)
Ẹ̀wádún 1990 náá ni àwọn ẹgbẹ́ olórin rap bíi Racionais MC’s bẹ̀rẹ̀ síi fí ojú hàn ní ilẹ̀ Brasil. Ìwà àti ìṣọwọ́ kọ̀rin àwọn rappers (afewìkọrin ìbìnú) fi ara jọ ti Itamar jọjọ nítorípé àdùgbò ìjọba-kò-rí-tiwa-rò ni àwọn náà ti dìdé bíí tirẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá kìí sìí fẹ́ ẹ rí imí tíwọn náà láàtàn. Èyí ló mú kí Itamar fẹ́ràn láti máa sọ wípé òun Nego Dito ní bábá ìsàlẹ̀ àwọn rappers tí o sì máa nṣe átìlẹyìn tó gbọungbọun fúnwọn gẹgẹbi ó ti hàn gbangba ní ilé àṣà àti ìkónkan ìṣẹ̀mbáyé  MU.ITA tí a gbé kalẹ̀ yìí lónìí.
Èèpo ẹ̀yìn àwo orin PretoBras, 1998. Fọ́tò: Sérgio Roizenblit
   
   
Isca de Polícia (Ìjẹ ọlọ́pàá)
Ẹ̀wádún 1990 náá ni àwọn ẹgbẹ́ olórin rap bíi Racionais MC’s bẹ̀rẹ̀ síi fí ojú hàn ní ilẹ̀ Brasil. Ìwà àti ìṣọwọ́ kọ̀rin àwọn rappers (afewìkọrin ìbìnú) fi ara jọ ti Itamar jọjọ nítorípé àdùgbò ìjọba-kò-rí-tiwa-rò ni àwọn náà ti dìdé bíí tirẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá kìí sìí fẹ́ ẹ rí imí tíwọn náà láàtàn. Èyí ló mú kí Itamar fẹ́ràn láti máa sọ wípé òun Nego Dito ní bábá ìsàlẹ̀ àwọn rappers tí o sì máa nṣe átìlẹyìn tó gbọungbọun fúnwọn gẹgẹbi ó ti hàn gbangba ní ilé àṣà àti ìkónkan ìṣẹ̀mbáyé  MU.ITA tí a gbé kalẹ̀ yìí lónìí.
 
'Itamar ti di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ fúnmi nípaṣẹ̀ ìrínísí rẹ̀ tó wúnilórí tó sì ndánílọ̀rùn nígbàgbogbo pẹ̀lú oge afro-futurista rẹ̀ tó jógun lọ́dọ̀ Sun Rá. Ìdúró rẹ̀ lọ́mọkùnrin pàápàá kò láfiwé. Èyí ló múmi yàn án láàyó gẹgẹbi àpẹẹrẹ ẹ̀wá tó dàpọ̀ mọ́ ìmúra oge tó jinnádénú.”
monica ventura
ka ọrọ kikun
 
Pretobrás II - Maldito Vírgula, 2005
 
Pretobrás III - Devia Ser Proibido, 2005

1990: Racionais MC’s gbé àwo EP àkọ́kọ́ “Holocausto Urbano” jáde - BRASIL 1990: Denise Assunção gbé àwo “A Maior Bandeira do Brasil” jáde - BRASIL 1991: Prince gbé àwo Diamonds and Pearls jáde - AMẸ́RÍKÁ1993: Ali Farka Touré gbé àwo “The Source” jáde - MALI1994: Jards Macalé gbé àwo “Let’s Play That” jáde pẹ̀lú Naná Vasconcelos  - BRASIL 1994: Nelson Mandela di Olórí orílẹ̀-èdè Africa do Sul – SOUTH ÁFÍRÍKÀ1993: Oumou Sangaré gbé áwo Ko Sira jáde - MALI 1996: Ella Fitzgerald kú - AMẸ́RÍKÀ 1990: Racionais MC’s gbé àwo EP àkọ́kọ́ “Holocausto Urbano” jáde - BRASIL 1990: Denise Assunção gbé àwo “A Maior Bandeira do Brasil” jáde - BRASIL 1991: Prince gbé àwo Diamonds and Pearls jáde - AMẸ́RÍKÁ1993: Ali Farka Touré gbé àwo “The Source” jáde - MALI1994: Jards Macalé gbé àwo “Let’s Play That” jáde pẹ̀lú Naná Vasconcelos  - BRASIL 1994: Nelson Mandela di Olórí orílẹ̀-èdè Africa do Sul – SOUTH ÁFÍRÍKÀ1993: Oumou Sangaré gbé áwo Ko Sira jáde - MALI 1996: Ella Fitzgerald kú - AMẸ́RÍKÀ 1990: Racionais MC’s gbé àwo EP àkọ́kọ́ “Holocausto Urbano” jáde - BRASIL 1990: Denise Assunção gbé àwo “A Maior Bandeira do Brasil” jáde - BRASIL 1991: Prince gbé àwo Diamonds and Pearls jáde - AMẸ́RÍKÁ1993: Ali Farka Touré gbé àwo “The Source” jáde - MALI1994: Jards Macalé gbé àwo “Let’s Play That” jáde pẹ̀lú Naná Vasconcelos  - BRASIL 1994: Nelson Mandela di Olórí orílẹ̀-èdè Africa do Sul – SOUTH ÁFÍRÍKÀ1993: Oumou Sangaré gbé áwo Ko Sira jáde - MALI 1996: Ella Fitzgerald kú - AMẸ́RÍKÀ

Grace Jones, 1977
Igbasilẹ Prop ti Itamar Assumpção lo, 2020
Itamar pẹ̀lú fọ́tò ìwé ẹ̀ri áti fọ́nrọ́n ìṣọ̀rọ̀ nibití o ti ndúpẹ́ fún àmì ẹ̀yẹ ọ̀kọrin tó dántọ́ jùlọ tí àjọ Associação Paulista de Críticos de Arte (APCA) fi dáa lọ́lá, 1998. Fọ́tò: Camila Gauditano.
“'Itamar ti di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ fúnmi nípaṣẹ̀ ìrínísí rẹ̀ tó wúnilórí tó sì ndánílọ̀rùn nígbàgbogbo pẹ̀lú oge afro-futurista rẹ̀ tó jógun lọ́dọ̀ Sun Rá. Ìdúró rẹ̀ lọ́mọkùnrin pàápàá kò láfiwé. Èyí ló múmi yàn án láàyó gẹgẹbi àpẹẹrẹ ẹ̀wá tó dàpọ̀ mọ́ ìmúra oge tó jinnádénú.”
monica ventura
ka ọrọ kikun
Atunse ti awo album Ataulfo ​​Alves nipasẹ
"Itamar Assumpção - Lailai ni bayi", 1993

   
   
 
 
Ney Matogrosso lórí ìtàgé níbi tó ti kọ orin "Atento aos Sinais" DVD
 
Cássia Eller níbí tó ti nkọ orin “Já Deu Pra Sentir” nínú ètò orí tẹ̀lifísọ̀n Metrópolis, 1991. TV Cultura.
 
tamar Assumpção nínú gèlè ìwérí aláfọwọ́hun tí Jairo Torres ṣe, 1981. Fọ́tò: Jairo Torres.
 
“ọ̀kọ̀rin pátàkì tí o tún jẹ́ ọmọlúàbí  àt” 
mano brown
ka ọrọ kikun
 
Èèpo ẹ̀yìn àwo orin Sobrevivendo no Inferno, dos Racionais Mc’s, 1997.
 
Itamar Assumpção àti Zélia Duncan, Fọ́tò Vera Motta
 
Itamar Assumpção, Chico César ati Jards Macalé
 
Luiz Melodia e Ita, 1992. Fọto: Juan Esteves (Aworan Folha)
“Iṣé akéwì i ̣ ṣé àmútò ̣ runwá ni. O dàbí ìpè làti òde ò ̣ run ti kò ̣ ṣeé ma jé, bi è ̣ nìyàn fé ̣ bó kò ̣ ̣ ó di dandan kó jéẹ̣ ni. Apẹẹrẹ tó fìdí èyi múlè pọ̀ jáñtir ̣ ẹẹ tí o fi ìdánilójú hàn gedeñgbe wipe, bíbí ní a mbí ènìyàn mó ̣ ị ṣé akéwì.”
alice ruIz
ka ọrọ kikun
Itamar Assumpção faramọ pẹlu Jandira, eni to ni igi bocce club ni Penha ati ọmọbinrin Jandira ni ibi idana

Penha de França ni adugbo keji ti o dagba julọ ni São Paulo, lẹhin Santo Amaro. Ẹnikẹni ti o ti ni igboya lati gba ọkọ oju-irin oju irin, Radial Leste tabi Marginal Tietê ki o lọ si Penha le loye idi ti Itamar Assumpção fẹran gbigbe nibẹ.

Ti o kun fun awọn irọra, awọn oke giga, awọn apeja, awọn ile itaja onjẹ ati awọn hovels, Penha ni ibi aabo pipe fun awọn ti o ni igberiko ni inu, fun awọn ti o dagba, Saci. Eyi jẹ ọkan ninu ọpọlọpọ awọn oju ti Ita, ti o nifẹ lati rin kakiri ni ita ibi ti a ti kọ Ile-ijọsin ni 1802 nipasẹ awọn obinrin ati awọn ẹru ẹrú, awọn ọmọ ẹgbẹ ti Arakunrin ti Nossa Senhora do Rosário dos Homens Pretos. Ni apa ọtun si Ile-ijọsin ni Ile-iṣere Martins Penna, ni Centro Cultural da Penha, ninu eyiti Ita ṣe ju ẹẹkan lọ.

Ni afikun si awọn aaye wọnyi ni “aarin kekere” atijọ ti adugbo, Itamar fẹran lati rin ati lọ si Sociedade Amigos de Vila Beatriz lati ṣe ere truco, bọọlu bocce ati lati lo akoko ni ile ọti Jandira. O wa nibẹ ni Agbegbe Ila-oorun pẹlu ẹbi rẹ lati ọdun 1976 titi di opin igbesi aye rẹ, ni ibọwọ fun apakan yii ti ilu ni iwọn II ti Bicho de Sete Cabeças Trilogy, pẹlu orin Ko si ẹnikan ti o mọ, ti o kun fun arinrin to dara.

Itamar Assumpção na Penha, ya aworan fun ara korokun lori ilẹkun ọkọ akero kan pẹlu seeti ti Zena ya, 1991
 
Igbasilẹ aworan ti seeti bulu ni ọwọ tailoring ya nipasẹ Zena, 2020
 

2000

Ní ọdún 2002, Ita ṣe eré ìtagbañgba kan pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Elke Maravilha tí o kọ orin Dor Elegante (Irora tó gbayì) tí Leminski ṣe àtinúda rẹ̀

“Elke mulher maravilha
Uma deusa pagã um sonar
Um altar uma trilha”

Àyọkà láti inú orin Elke Mulher Maravilha nínú àwo Pretobrás I, 1998

Ní ọdún 2003 ni Itamar jáde láye lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí o ti mbá àìsàn jẹjẹrẹ̀ wọ̀yá ìjà. Itamar kú níti ara, ṣùgbọ́n kò kú àkúrun nítorí o ti ṣe ohun manigbàgbé sílé ayé. Ní ọdún kejì lẹ́hìn tó tí rèwàlẹ̀àṣà ní a gbé àwo orin rẹ̀ tí ó ṣe pẹ̀lú Naná Vasconcelos jáde, àkọlé àwo náà ni Isso vai dar Repercussão (Ọ̀rọ̀ yí máa lẹ́yìn). Àwo yìí ní Itamar bẹ̀rẹ̀ síí ṣiṣẹ lé lórí nígbàtí o ngba ìtọ́jú lọ́wọ́. Paulo Lepetit áti Bocato ni wọ́n parí iṣẹ́ lórí àwo náá.

Itamar ríi dájú wípé kí òun tó jáde láyé o fí ojú kan ọmọ-ọmọ rẹ̀ ti njẹ́ Rubi, tíi ṣe ọmọ àkọbi fún  ọmọ rẹ̀ Anelis Assumpção. A bí ọmọ náà ni ọdún 2002.

Ní ọdún 2005, Clara Bastos ṣe àkójọpọ̀ àwọn iṣẹ́ tí Itamar fi sáyé lọ gẹgẹbí ohun tí Itamar fúnra rẹ̀ tiṣe sọ kó tóó kú. Clara Bastos ṣe àdàkọ gbogbo orin Itamar, nigbàtí Luiz Chagas òun Mônica Tarantino sì ṣe àgbéjáde iṣẹ́ náà nínú ìwé méjì tí wọ́n pè àkọlé rẹ̀ ní Pretobrás - Por que que eu não pensei nisso antes? (Brasil Dúdú – Kíniṣe tí míò ti ronú dẹ́bẹ̀ láti ìgbà yì wá?). Àkọlé kéjì tí a fún ìwé náà ni Ìwé orin àti ìtàn ìgbésí ayé Itamar Assumpção.

Ni ọdún 2006, Ana Maria Gonçalves ṣe àgbéjáde ìwé onítàn rẹ̀ tí ó pè ní Um defeito de Cor (Àbàwọ́n).

Èèpo ẹ̀yìn àwo orin Isso Vai dar Repercussão, 2004.
   
▶   OUÇA
   
Itamar Assumpção àti Elke Maravilha lórí ìtàgé SESI, 2002. Fọ́tò: Mila Maluhy.
 
Itamar Assumpção gbé Rubi, ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, 2002.
 
Díẹ̀ lára àwọn fọ́tò Itamar Assumpção áti Naná Vasconcelos, 2000. Fọ́tò: Angela Prada.
Itamar Assumpção àti Elke Maravilha lórí ìtàgé SESI, 2002. Fọ́tò: Mila Maluhy.

2001: Tinariwen gbé àwo “The Radio Tisdas Sessions” jáde - MALI 2003: Chimamanda Adichie gbé ìwé “Hibisco Roxo” jáde - NIGERIA 2003: Conceição Evaristo gbé ìwé “Ponciá Vicêncio” jáde - BRASIL2004: Konono nº1 gbé àwo “Congotronics” jáde  - CONGO 2004: A dá Mùsọ́ọ̀mù Aláwọ̀ Dúdú (Museu Afro Brasil) silẹ̀ ni São Paulo - SP -BRASIL2009: . Lupita Nyong'o kọ ìwé sinimá onítàn o sì gbé sinima My Genes jáde – AMẸ́RÍKÁ2009: Rosana Paulino sí àfihàn Roots and More: The Journey of the Spirits – BRASIL 2001: Tinariwen gbé àwo “The Radio Tisdas Sessions” jáde - MALI 2003: Chimamanda Adichie gbé ìwé “Hibisco Roxo” jáde - NIGERIA 2003: Conceição Evaristo gbé ìwé “Ponciá Vicêncio” jáde - BRASIL2004: Konono nº1 gbé àwo “Congotronics” jáde  - CONGO 2004: A dá Mùsọ́ọ̀mù Aláwọ̀ Dúdú (Museu Afro Brasil) silẹ̀ ni São Paulo - SP -BRASIL2009: . Lupita Nyong'o kọ ìwé sinimá onítàn o sì gbé sinima My Genes jáde – AMẸ́RÍKÁ2009: Rosana Paulino sí àfihàn Roots and More: The Journey of the Spirits – BRASIL 2001: Tinariwen gbé àwo “The Radio Tisdas Sessions” jáde - MALI 2003: Chimamanda Adichie gbé ìwé “Hibisco Roxo” jáde - NIGERIA 2003: Conceição Evaristo gbé ìwé “Ponciá Vicêncio” jáde - BRASIL2004: Konono nº1 gbé àwo “Congotronics” jáde  - CONGO 2004: A dá Mùsọ́ọ̀mù Aláwọ̀ Dúdú (Museu Afro Brasil) silẹ̀ ni São Paulo - SP -BRASIL2009: . Lupita Nyong'o kọ ìwé sinimá onítàn o sì gbé sinima My Genes jáde – AMẸ́RÍKÁ2009: Rosana Paulino sí àfihàn Roots and More: The Journey of the Spirits – BRASIL

Ṣe afihan Vozes ṣe Brasil, 2000s. Fọto: Mila Maluhy
Igbasilẹ aworan ti awọn aṣọ-aṣọ ti Itamar ti a ṣe lati awọn aṣọ inura lati ile-iwosan aarun, nigbati o wa labẹ itọju, 2020
Awọn aworan orchids ti Itamar ati Zena ṣe agbe ni ile wọn ni Penha
Iwe-ipamọ "Lati akoko yẹn siwaju", 2011, oludari ni Rogério Veloso

2010

Ní ọdún 2010, ilẹ́ ìgbórinjáde tí a mọ̀ sí Selo Sesc ṣe àtúntẹ̀ gbogbo àwọn àwo Itamar Assumpção, tí wọ́n sìtún ṣe àfikún àwo méjì tuntun láti kún àwo onígamẹ́ta Pretobrás Apá II - Maldito Vírgula, tí Beto Villares kọ áti Apá III - Devia Ser Proibido, tí Paulo Le Petit kọ.

Ní ọdún 2011 Rogério Velloso tíí ṣe olùdari sinimá gbé eré sinimá kan jáde ti ó pè ni  Daquele Instante em Diante (Lati ìgbà náà lọ) nínú èyi tí ó ti ṣe àfihàn ìgbésí ayé Itamar Assumpção àti gbogbo iṣẹ́ olórin rẹ̀ pẹ̀lú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó ṣe fún àwọn alábàṣiṣẹ́pọ̀ Itamar áti àwọn ẹbi

Ọdún yì kánnáà ní a bí Benedito – ọmọ àbíṣìkejì Anelis tí ìyá rẹ̀ sọ ní orúkọ náà ní ìrántí bàbá rẹ̀ àgbà.

Ní ọdún 2013 ní a gbé ìwé "Cadernos Inéditos" (àkọsílẹ̀ àkọ̀tun) nínú èyi tí a ti ṣe àkójọpọ̀ gbogbo orin áti àwọn àkọsílẹ̀ Itamar Assumpção míràn bíi ewì, orin àti àròkọ. Ìwé náà ni a gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ Anelis áti Serena Assumpção pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Elizena Assumpção òun Marcelo Del Rio tíí ṣe agbórinkálẹ̀ àti ọ̀rẹ̀ ìdìlé Itamar.

Ni ọdún 2014 ní àwòrán àpilẹ̀ṣe Reverberações jáde èyí tí ó dá lórí iṣẹ́ Itamar Assumpção. Cláudia Pucci àti Pedro Colombo ló gbé e jáde.

Ni ọjọ́ kẹrìndínlógún osù kẹta ọdún 2016, Serena tíi ṣe àkọ́bí ọmọ Itamar náà filẹ̀ ṣaṣọ bora lẹ̀hìn tí òun náà tí ṣiṣẹ́ takuntakun lókè eèpẹ̀. Àwo orin rẹ̀ Ascensão (ìgòkè) ní iṣẹ́ rẹ̀ kan gbòógì tí ó dá lóri ẹ̀sìn òrìṣà tí a mọ̀ sí Candomblé. Serena tí pari iṣẹ́ náà tán kó tóó kú, a sì gbé e jáde ni kété tó kú tán tí àwo ọ̀ún sì gbà àmi ẹ̀yẹ Grammy Latino gẹ́gẹ́bí àwo tó dára júlọ̀ ni ilẹ̀ Brasil. Ọdún yìí kannáà ní Naná Vasconcelos kú, ọ̀ṣẹ̀ kan péré ló làwọ́n láàrín.

Ni ọdún 2019 tí Itamar Assumpção ìbá pé ọmọ àádọrin ọdún, a ṣe ogunlọ́gọ̀ ètò ní ìrántí rẹ̀ nínú èyi tí a ti rí ìjìròrò àti orin tí o milẹ̀ jìjì tí ó wáyé ni São Paulo, tí a pè ni Virada Cultural.

Lọ́dún yìí kan náà, ni a kọ́kọ́ ṣe eré Pretoperitamar (Itamar ògbólógòó aláwọ̀ dúdú), tíí ṣe arédórin (opera) nínú èyi tí a ti ṣọ ìtàn ìgbésí ayé Itamar láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Grace Passô ló dári eré náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ana Maria Gonçalves, tí Anelis Assumpção sì ṣe agbátẹrù rẹ́.

Ọdún 2019 ni Spike Lee gba ámi ẹ̀yẹ Oscar rẹ̀ àkọ́kọ́ fún sinima Infiltrado na Klã (ọlọ́fintótó Klã).

GBỌ̀NGÀN SERENA >

Photoshoot fun ifihan ti Pretoperitamar Musical, 2019
 
Caixa Preto (Apoti Dudu) pẹlu iṣẹ pipe ti Itamar, ti ṣe ifilọlẹ ni ọdun 2010 nipasẹ Sesc

2013: A dá àjọ àgbáyé Black Lives Matter / Vidas Negras Importam/ Ẹ̀mì Ènìyàn Àláwọ̀ Dúdú ṣe Pàtàkì  sílẹ̀ – ‘ÀMẸ́RÍKÀ2014: Juçara Marçal gbé àwo “Encarnado” jáde - BRASIL2015: Liniker áti Os Caramelows gbé àwo orin  EP “Cru” jáde - BRASIL 2016: Beyoncé gbé àwo orin “Lemonade” - AMẸ́RÍKÀ2016: Serena Assumpção gbé àwo orin “Ascensão” jáde - BRASIL2017: Djamila Ribeiro gbé ìwé “O que é Lugar de Fala?” jáde - BRASIL2017 :A sí Musọ́ọ̀mù  Zeitz Museum of Contemporary Art Africa - AFRICA DO SUL 2018: Àwọn agbébọn ṣe ikú pa arábìnrin olóṣèlú Marielle Franco ní Rio - BRASIL2018: Érica Malunguinho di ọkùnrin-tó-di- obìnrin àkọ́kọ́ ti a dìbò yàn sí ilé àsojú-sòfin - BRASIL 2018: Anelis Assumpção gbé àwo orin “Taurina” jáde - BRASIL2019: “Baco Exu do Blues” gbá àmì ẹ̀yẹ sinima ni Cannes pẹ̀lú áwo orin “Bluesman” - BRASIL 2019: Okwui Enwezor, Alábòjúto Musọ́ọ̀mú nlá di olóògbé - NIGERIA 2013: A dá àjọ àgbáyé Black Lives Matter / Vidas Negras Importam/ Ẹ̀mì Ènìyàn Àláwọ̀ Dúdú ṣe Pàtàkì  sílẹ̀ – ‘ÀMẸ́RÍKÀ2014: Juçara Marçal gbé àwo “Encarnado” jáde - BRASIL2015: Liniker áti Os Caramelows gbé àwo orin  EP “Cru” jáde - BRASIL 2016: Beyoncé gbé àwo orin “Lemonade” - AMẸ́RÍKÀ2016: Serena Assumpção gbé àwo orin “Ascensão” jáde - BRASIL2017: Djamila Ribeiro gbé ìwé “O que é Lugar de Fala?” jáde - BRASIL2017 :A sí Musọ́ọ̀mù  Zeitz Museum of Contemporary Art Africa - AFRICA DO SUL 2018: Àwọn agbébọn ṣe ikú pa arábìnrin olóṣèlú Marielle Franco ní Rio - BRASIL2018: Érica Malunguinho di ọkùnrin-tó-di- obìnrin àkọ́kọ́ ti a dìbò yàn sí ilé àsojú-sòfin - BRASIL 2018: Anelis Assumpção gbé àwo orin “Taurina” jáde - BRASIL2019: “Baco Exu do Blues” gbá àmì ẹ̀yẹ sinima ni Cannes pẹ̀lú áwo orin “Bluesman” - BRASIL 2019: Okwui Enwezor, Alábòjúto Musọ́ọ̀mú nlá di olóògbé - NIGERIA

Ita70 Ipele ni Virada Cultural ti São Paulo, 2019
Pretoperitamar, Sesc Pompéia, São Paulo, 2019

2020

Ni ọdún tí a wà yìí, iṣẹ́ àti orúkọ Itamar Assumpção tún ngbòòrò síi. Pàtàkí àti ìwúrí ló jẹ́ fúnwa láti ṣe àgbékalẹ̀ mùsọ́ọ̀mú ilé àṣà àkọ́kọ́ lóri ẹ̀rọ ayélujára tí a fi sọrí ènìyàn àláwọ̀ dúdú nílẹ̀ yìí tí a pe orúkọ rẹ̀ ni MU.ITA.

Yàtọ̀sí ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Embratel, àwọn tekinọ́lọ́jì àtínúdà àti àgbélẹ̀rọ ìran aláwọ̀ dúdú ní a fí gbé ilé àṣà ọ̀ún kalẹ̀ láti lè ríi dájú wípé ìgbésí ayé Itamar àti iṣe takuntakun rẹ̀ kò di ohun ìgbàgbé nílẹ̀ yìí àti lágbàyé.

Ideri ti EP Beleléu nipasẹ Embratel, ti a tu ni 2020
   
▶   OUÇA
   
Eto Pretoperitamar, 2019
 
Agekuru pẹlu awọn aworan lati MU.ITA fun ẹyọkan "Beleléu Via Embratel". Itọsọna: Parteum. São Paulo, 2020.

2020: Ọlọ́pa aláwọ̀ funfun kan ṣekú pa George FLoyd ọmọ aláwọ̀ dúdú lọ́ọ̀nà áìtọ́ni ilẹ̀ AMẸ́RÍKÁ 2020: Negro Léo gbé àwo orin “Desejo de Lacrar” jáde - BRASIL2020: Luedji Luna gbé ìwé “Bom Mesmo É Estar Debaixo D’água” jáde - BRASIL 2020: Jaqueline Goes kópa tó jọjú nínú ìwàdi sáyẹ́nsì láti rídi àìsàn coronavírus - BRASIL 2020: Ọlọ́pa aláwọ̀ funfun kan ṣekú pa George FLoyd ọmọ aláwọ̀ dúdú lọ́ọ̀nà áìtọ́ni ilẹ̀ AMẸ́RÍKÁ 2020: Negro Léo gbé àwo orin “Desejo de Lacrar” jáde - BRASIL2020: Luedji Luna gbé ìwé “Bom Mesmo É Estar Debaixo D’água” jáde - BRASIL 2020: Jaqueline Goes kópa tó jọjú nínú ìwàdi sáyẹ́nsì láti rídi àìsàn coronavírus - BRASIL 2020: Ọlọ́pa aláwọ̀ funfun kan ṣekú pa George FLoyd ọmọ aláwọ̀ dúdú lọ́ọ̀nà áìtọ́ni ilẹ̀ AMẸ́RÍKÁ 2020: Negro Léo gbé àwo orin “Desejo de Lacrar” jáde - BRASIL2020: Luedji Luna gbé ìwé “Bom Mesmo É Estar Debaixo D’água” jáde - BRASIL 2020: Jaqueline Goes kópa tó jọjú nínú ìwàdi sáyẹ́nsì láti rídi àìsàn coronavírus - BRASIL 2020: Ọlọ́pa aláwọ̀ funfun kan ṣekú pa George FLoyd ọmọ aláwọ̀ dúdú lọ́ọ̀nà áìtọ́ni ilẹ̀ AMẸ́RÍKÁ 2020: Negro Léo gbé àwo orin “Desejo de Lacrar” jáde - BRASIL2020: Luedji Luna gbé ìwé “Bom Mesmo É Estar Debaixo D’água” jáde - BRASIL 2020: Jaqueline Goes kópa tó jọjú nínú ìwàdi sáyẹ́nsì láti rídi àìsàn coronavírus - BRASIL

2030

Ọ̀na wo ní iṣẹ́ Itamar tún máà gbà láti ran ìran tuntun tó mbọ̀ lọ́wọ́ ni ọjọ́ iwájú, nípàtàkí ìran aláwọ̀ dúdí ilẹ̀ Brasil?

Itamar tí à nsòrọ̀ rẹ̀ yìí ni Itamar tí ó wà ni agbedeméjì ayé òun ò ̣ run, ̣ èyí tí o jásí òkannáà. Òun náà ní a fé ̣ ̣ṣe àfihàn rè bí ewì aládùn fún ayé gbó ̣ , ọ̀ rọ̀ ewì tí ̣ ngbénú ẹran ara láláì jókòjéẹ́ , ọ̀ rọ̀ ìjìnlè ̣ oníga méjì tó kalè ̣ sí ìkóríta mé ̣ ta àlá àró ̣ ọ̀ rọ́ tán ̣ olóòrùn òdòdó.
TIGANÁ SANTANA
ka ọrọ kikun
Itamar tí à nsòrọ̀ rẹ̀ yìí ni Itamar tí ó wà ni agbedeméjì ayé òun ò ̣ run, ̣ èyí tí o jásí òkannáà. Òun náà ní a fé ̣ ̣ṣe àfihàn rè bí ewì aládùn fún ayé gbó ̣ , ọ̀ rọ̀ ewì tí ̣ ngbénú ẹran ara láláì jókòjéẹ́ , ọ̀ rọ̀ ìjìnlè ̣ oníga méjì tó kalè ̣ sí ìkóríta mé ̣ ta àlá àró ̣ ọ̀ rọ́ tán ̣ olóòrùn òdòdó.
TIGANÁ SANTANA
ka ọrọ kikun
 
Awọn fọto: Vania Toledo
Ideri ti awo-orin Missa ni Memoriam, Arrigo Barnabé, 2003
Itamar Assumpção ati Luis Melodia ṣe ere orin kan
Fọto: Rubens Chaves

NI ÌRÁNTI

A tún fi ìfihàn yìí ṣe àyẹ́sí fún Vânia Toledo, ayáfọ́tò tí o ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Itamar nígbà aye rẹ̀ tí o sì tẹ̀lée lọ sí gbogbo ibi ere rẹ̀. (Paracatu, ọjọ́ kọkándínlọ́gbọ̀n osù kínní ọdún 1945 — São Paulo, ọjọ́ kẹ́rìndínlógún osù keje ọdún 2020)
Gigante Brazil (Rio de Janeiro, ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n osù kerin ọdún 1952, São Paulo, Ogúnjọ́  osù kẹsàn ọdún 2008)
Naná Vasconcelos (Recife, ọjọ́ kejì osù kẹjọ ọdún 1944 — Recife, ọjọ́ kẹsán osù kẹta ọdún 2016)
Luiz Melodia (Rio de Janeiro, ọjọ́ keje osù kínní ọdún 1951 – Rio de Janeiro, ọjọ́ kẹrin osù kẹjọ ọdún 2017)
Gbogbo ipa ni a ti ṣe lati kan si awọn ti o ni ẹtọ awọn aworan. Ni ọran ti omission, a yoo ṣe gbogbo awọn atunṣe to ṣeeṣe ni aye akọkọ. Eyi jẹ ikede ti kii ṣe èrè, o si wa laaye ti awọn isanwo aṣẹ-lori ara ni Ilu Brazil, ni aabo nipasẹ Ofin Bẹẹkọ 9,610, Akọle III, Abala Kẹrin, Ẹran 46, Nkan VIII.

ILÉ-ÌTAJÀ

ÌRÀNLỌ́WỌ́

ALÁWỌ̀ DÚDÚ ILẸ̀ BRASIL ALÁÌLÁBÀWỌ́N NI MO JẸ́

YO